Banditry in Nigeria: Ilé ẹjọ́ kéde àwọn jàndùkú gẹ́gẹ́ bíi agbésùmọ̀mí

bandits

Oríṣun àwòrán, facebook/Offiong Enoh

Ile ejọ giga kan niluu Abuja ti kede awọn janduku gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọmi.

Nigba to n ṣedajọ lori ọrọ naa, adajọ Taiwo Taiwo sọ pe awọn iwa ati iṣesi awọn ẹgbẹ janduku ti orukọ wọn n jẹ Yan Bindiga ati Yan Ta'adda jẹ ti igbesumọmi.

Idajọ yii lo waye lẹyin ẹjọ ti ijọba apapọ pe lati ipasẹ ileeṣẹ to n ri si eto idajọ.

Ijọba apapọ sọ ninu iwe ipẹjọ naa pe iwadii awọn fi han pe awọn janduku naa lo wa nidii oniruru ipaniyan, ifipabanilopọ, ijinigbe atawọn iwa ọdaran mii lapa Ariwa Naijiria.

O ni awọn naa lo wa nidi ijinigbepawo, ati ijinigbe pẹlu erongba lati fi agidi fi obinrin fun ọkọ ti inu wọn ko yọ si, fifi ẹran jẹko, ifiyajẹni, ijinigbe awọn akẹkọọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ikọ olupẹjọ sọ fun ile ẹjọ naa pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu erongba lati kede awọn janduku ọhun gẹgẹ bii agbesumọmi.

Àkọlé fídíò, Gbọ́ ohun ti àwọn òṣèré tíátà Yoruba sọ fún BBVC nípa Baba Suwe

Lẹyin naa ni adajọ Taiwo Taiwo gba ẹbẹ naa wọle to si kede ẹgbẹ Yan Bindiga, ẹgbẹ Yan Ta'adda atawọn ẹgbẹ mii kaakiri Najiria, paapaa lapa iha Ariwa Naijiria gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesumọmi.

Ile ẹjọ naa tun kede gbogbo iṣe awọn janduku ọhun gẹgẹ bii eyii to lodi si ofin ni Naijiria.

Lẹyin idajọ naa ni adajọ Taiwo Taiwo wa paṣẹ ki ijọba apapọ fi ikede sita pe awọn janduku ti di agbesumọmi ni Naijiria ninu iwe iroyin meji to lamilaaka ati ninu iwe ti wọn ti n kede awọn iṣẹ kanṣe ijọba apapọ.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí