Adesina Ogunlana: Ìjọba kò mọ̀ pé ikọ̀ olùwádìí EndSARS yóò sọ òtítọ̀ ló fi gbe kalẹ̀

Àkọlé fídíò, Adesina Ogunlana: Ìjọba kò mọ̀ pé ikọ̀ olùwádìí EndSARS yóò sọ òtítọ̀ ló fi gbe kalẹ̀

Adesina Ogunlana, tii se amofin fun awọn oluwọde EndSARS ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti Lai Muhammed sọ lori abọ igbimọ oluwadii isekupani to waye ni Lekki.

Ninu ọrọ rẹ, Ogunlana ni ijọba apapọ ko mọ pe ikọ oluwadii isekupani to waye ni Lekki yoo sọ otitọ ni, bibẹẹkọ, ko ba ti gbe igbimọ naa kalẹ.

O ni wọn ko mọ pe awn olotitọ ẹda si wa ni Naijiria, ti yoo sọ bi ọrọ se jẹ lai jẹ ki ijọba dari wọn sibi to wu wọn.

Ogunlana wa se apejuwe minisita feto iroyin, Lai Muhammed gẹgẹ bi ni to n si ijọba apapọ lọna.

O ni Lai Muhammed lo n jẹ ki ijọba apapọ kọ ẹyin si ibi tawọn ọmọ Naijiria kọju si, eyi to n ko ifasẹyin ba orilẹede yii.

O wa se apejuwe bi ijọba apapọ se fọwọ osi rọ abọ iwadi igbimọ oluwadi naa danu gẹgẹ bii iwa ẹtanu to lagbara.