Ogun Tanker explosion: Òhun táa mọ̀ nípa ìbúgbàmù ọkọ̀ aképo ní Lafenwa l'Òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú réè

Aworan Ibugbamu to waye

O kere tan eeyan mẹta la gbọ pe o ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina kan to waye ni Lafenwa lẹba reluwee ni Abeokuta.

Ninu wọn la gbọ pe abiyamọ kan ọmọ rẹ ati eeyan kan lojo raurau ninu ijamba ina yi.

Ijamba ina yi to ṣẹyọ latara ibugbamu ọkọ agbepo kan to subu lulẹ la gbọ pe o jo awọn sọọbu ni agbegbe naa tawọn eeyan mi si farapa.

Ninu alaye ti atẹjade kan lati ọdọ ajọ to n mojuto lilọ bibọ ọkọ loju popo ni Ogun TRACE ti se sọ,aigbọran awọn eeyan to fẹ gbọn epo to n san danu lo fa iṣẹlẹ yi.

Ọga ajọ naa Babatunde Akinbiyi sọ pe ''awọn to kọ eti ikun ti wọn fẹ gbọn epo lo mu ki ọkọ agbepo naa to ṣaaju subu lulẹ gbina''

Yatọ si ina yi taa gbọ pe o jo awọn ṣọọbu lagbegbe naa, iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe niṣe lawọn janduku kan n fọ sọọbu ti wọn si n ji nkan gbe nibẹ.

Lowurọ ọjọ Aiku ni ọkọ agbepo yi ti ṣubu danu soju ọna reluwee lagbegbe Lafenwa ti epo si bẹrẹ si ni danu silẹ.

TRACE ṣalaye pe awọn ati ikọ ọlọpaa to fi mọ ajọ FRSC de sibẹ lati ri pe lilọ bibọ ọkọ lagbegbe naa ko da wahala silẹ.

Akọroyin wa to wa lagbegbe naa sọ pe wọn ti ribi pa ina naa ṣugbọn ko ti si iroyin pato lori iye awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.