Jos Prison Break: Kíni yóò gbẹ̀yìn àwọn agbébọn tó há sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Jos tí wọ́n ṣígun bo?

Oríṣun àwòrán, other
Iroyin eleyi dabi igba ti eeyan n wo ere sinima Nollywood ṣugbọn lootọ lo ṣẹlẹ.
Awọn agbebọn kan to yabo ọgba ẹwọn to wa ni ilu Jos ti ha sinu ọgba ẹwọn tawọn agbofinro si ti yi wọn ka.
Lọjọ Aiku yi ni nkan bi ago marun un irọlẹ kọja lawọn alaburu yi ṣigun lọ si ọgba ẹwọn naa.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọgba ẹwọn Naijiria Francis Enobore fi sita, o ni niṣe lawọn agbebọn naa dira wa ti wọn si ko orisirisi ibọn wa sibẹ.
O ni wọn ribi wọ inu ọgba nla ẹwọn naa lẹyin ti wọn doju ija kọ awọn ẹsọ to wa lẹnu ọna.
Ko pẹ ti wọn ribi wọ inu ọgba yi lawọn agbofinro lati ileeṣẹ alaabo de lati wa ran awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa lọwọ ti wọn si ṣe wọn mọ inu ọgba naa.
Enobore sọ pe awọn ti n ribi bori awọn agbebọn yi ti ọtta wọn ko si ni pe tan.
Ko sọ boya eeyan kankan faragbọta ninu iṣẹlẹ yala lara awọn ẹsọ to wa ni ọgba naa tabi awọn agbebọn.
O ni kete tawọn ba yanju wahala to wa nilẹ yi lawọn yoo fi to araalu leti.
Iṣẹlẹ ikọlu si ọgba ẹwọn ni Naijiria kii se nkan tuntun paapa lasiko yi ti orileede naa n kojuipenija aabo.
Laipẹ yi ni awọn agbebọn ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn ni Kabba ati eleyi to wa ni Abolongo ni ilu Oyo.













