Oduduwa Republic: Banji Akintoye kọ̀wé-fipò sílẹ̀ bíi alága ẹgbẹ́ NINAS,Òhun tó mú ṣé bẹ́ẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, others
Ede aiyede to n waye laarin agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ajijagbara lapa Guusu Naijiria NINAS, ti tubọ gbilẹ si.
Ọrọ na ti awọn onwoye ohun to n lọ ro pe yoo yanju laipẹ ti gbọna mii yọ ni bayii ti alaga ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Banji Akintoye kọwe fi ipo rẹ silẹ.
Awọn ẹgbẹ to wa ninu NINAS ni ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, to n ṣoju ẹya Yoruba, ati ẹgbẹ Lower Niger Congress, LNG, to n ṣoju ẹya Igbo.
- Ẹ̀mí Ọlọ́pàá àti ọ́ọ́físà àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó bó níbi idigunjale Banki tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé ní Aramoko Ekiti
- Bimpe Oyebade sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí àwọn èèyàn tó ń lọgun pé ó lóyún
- Wọ́n yọ ẹ̀yà ara màmá wa tí wọn pa ní ṣọ́ọ́ṣì Deeper lọ - Ẹbí pariwo
- Wo Sẹ́nétọ̀ tó fẹ́ gbé bùkátọ̀ iléẹ̀kọ́ ìbejì Timithy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
Bakan naa ni ẹgbẹ Middle-Belt Rennaissance Movement, MRM naa to n sọju awọn ẹya to wa ni aarin gbungbun Naijiria wa lara wọn.
Ọjọgbọn Akintoye ni oun kọwe fi ipo alaga NINAS silẹ nitori awọn kan lara awọn adari ẹgbẹ naa ti n ṣiṣẹ lodi si ohun ti ẹgbẹ ọhun duro fun.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, Akintoye atawọn agbagba mẹrinlelogoji mii sọ pe o ṣe Pataki ki ẹka Yoruba yapa kuro ninu NINAS nitori ohun ti ẹgbẹ Ilana Omo Oodua duro fun ati afojusun rẹ.
Atẹjade naa ni "Nitori ibi ti ọrọ de duro nipa ijijagbara ọmọ Yoruba kuro ni Naijiria, paapaa ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, o ṣe Pataki fun wa lati kuro ninu ẹgbẹ NINAS ni kiakia."
"Igbagbọ wa ni pe awọn kan ninu ẹgbẹ NINAS ti a n ba ṣe ko nifẹ si irufẹ ominira ti awa ọmọ Yoruba n fẹ."
"Nitori naa, awa adari ẹgbẹ Ilana Omo Oodua fẹ fi akoko yii kede pe a ti yọ ara wa kuro lara NINAS."
Lẹyin naa ni wọn dupẹ lọwọ Ọgbẹni Tony Nnadi fun akitiyan rẹ gẹgẹ bii aṣaaju ẹgbẹ ẹya Igbo, LNC, ati akitiyan rẹ lati gbe ẹgbẹ NINAS ro.
Ṣugbọn wọn ni kii ṣe ohun kan naa ni ẹgbẹ LNC ati Ilana Omo Oodua n fẹ, idi ree ti ibaṣepọ awọn fi gbọdọ dopin.
Ilana Omo Oodua tẹsiwaju pe awọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ NINAS mọ lati akoko yii lọ.
Amọ ṣa, Ilana Omo Oodua ni awọn yoo kede ibaṣepọ tuntun mii laipẹ to jẹ agbarijọpọ ẹya to n pe fun ominira ni iha Guusu ati arigbungbun Naijiria, SOMPSOM.














