Customs Vs Bilionaires: A kò mọ ohunkóhun nípa ọkọ̀ òfúrufú 91 tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ gbẹ́sẹ̀lé – FAAN, NCAA

Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé bàálù awọn èèyàn jàǹkàn 91 wọ́n ni wọn ò san owó gbígbé wọlé

Oríṣun àwòrán, Vistajet.com

Ileeṣẹ to n ri si wọle-wọde ni Naijiria, NCS, ti sọ pe kii ṣe pe awọn kan dede gbẹsẹle awọn ọkọ ofuru awọn eeyan kan ni Naijiria.

Ṣugbọn wọn ni awọn ṣe bẹẹ nitori awọn ti ọrọ naa kan ko tẹle ofin to rọ mọ gbigbe ọkọ baalu aladani wọle si Naijiria.

Alukoro ileeṣẹ naa, Joseph Attah lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan.

O ni kii ṣe pe awọn fẹ mọọmọ fi iya jẹ awọn to ni ọkọ baalu naa, ṣugbọn o ti ṣe diẹ ti awọn ti n lọgun rẹ fun awọn ti ọrọ naa lati wa ṣe ohun to tọ lori ọkọ ofurufu wọn.

Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé bàálù awọn èèyàn jàǹkàn 91 wọ́n ni wọn ò san owó gbígbé wọlé

Oríṣun àwòrán, Dailypost

Gẹgẹ bii ohun to sọ, pẹlu ọna ẹburu ni awọn mii lara awọn to ni ọkọ ofurufu naa gba ko wọn wọle.

O ni "Awọn mii sọ fun ijọba pe o ni iye ọjọ ti ọkọ ofurufu naa yoo lo ni Naijiria ki wọn to gbe pada si orilẹ-ede mii, leyii to n tumọ si pe wọn ṣi maa pada gbe wọle si Naijiria lọna to tọna."

"Ṣugbọn ti wọn ba ti de Najiria tan ni wọn yoo bẹ ijọba pe ko fun wọn ni anfani ọjọ diẹ si."

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

"Lati ibẹ lọ, awọn mii yoo bẹrẹ si n lo ọkọ ofurufu naa labẹle lai pada wa lati ṣe awọn iforukọsilẹ to yẹ ki wọn ṣe ati lati san awọn owo to yẹ ki wọn san labẹ ofin."

Attah ṣalaye pe o ti to oṣu meloo kan sẹyin ti awọn ti n ke si awọn ti ọrọ naa kan lati wa ṣe ohun to yẹ ṣugbọn wọn ti sun ijọba kan ogiri.

Ni ti ohun ti ileeṣẹ aṣobode yoo ṣe ti awọn ti ọrọ kan ba kọ lati san awọn owo ti wọn n bere fun, eyii ti o to ọgbọn biliọnu naira , o ni oun ko ni sọ ohun ti awọn yoo ṣe bayii ṣugbọn awọn yoo tẹle ofin.

Bakan naa lo kọ lati mẹnu ba awọn eeyan ti ọrọ yii kan.

Ẹwẹ, ileeṣẹ to n mojuto igbokegbodo ọkọ ofurufu ni Naijiria, NCAA, ati ileeṣẹ ijọba apapọ to n ṣakoso papakọ ofurufu, FAAN ti sọ pe awọn mọ ohunkohun nipa awọn ọkọ ofurufu ti ijọba ni ki wọn gbẹsẹle.

Awọn agbẹnusọ ileeṣẹ mejeji lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo.

Bi agbẹnusọ NCAA ṣe sọ pe ọrọ naa kii ṣe ojuṣe ileeṣẹ oun, naa ni agbẹnusọ FAAN sọ pe wọn ko tii fi ọrọ ọhun to oun leti.

Ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀lé bàálù àwọn èèyàn jàǹkàn 91, wọ́n ni wọn ò san owó orí ẹ̀

Àwọn pásítọ̀ ìjọ ńláńnlá, awọn onísòwò jànkan, ọga ilé ìfowópamọ́ àti elépo rọ̀ọ̀bì tó fi mọ́ àwọn aláṣẹ ni NCAA, FAAN, NAMA ní ọ̀rọ̀ yìí kàn.

Ìjọba àpapọ̀ ti paa láṣẹ pé ki àjọ aṣọ́bode ni Nàìjíríà wa àwọn ọkọ̀ ofurufú aládani mọ́kànléláádọ́run gúnlẹ nítorí wan kọ láti san owó orí lórí ẹ.

Owó orí ti ó yẹ ki ìjọba rí lórí awọn ọkọ̀ náà ń lọ bi bílíọ̀nù lọ́nà ọgbọ̀n nàírà gẹ́gẹ́ bi àkọsílẹ̀ ṣe sọ.

Àkọlé fídíò, Afeez Akintunde: Àwọn ẹbí Tula Oyo figbe tá pé kò ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú Yoruba Nation

Nítorí ìdí èyí, ọ̀gá àgbà ní ilé iṣẹ́ aṣọ́bodè Nàìjíríà, Col. Hameed Ali láti tẹ̀lé àṣẹ ààrẹ Muhammadudu Buhari ti ni kí àjọ aṣọbode fi ofin de àwọn ọkọ náà lóní wàrànṣesà.

Iwé ti wọ́n kọ ránṣẹ láti kéde lọ́jọ́ kejì oṣù kọkànlá ọdún yii si adarí àjọ NCAA Musa Nuhu ni NCS/T&T/ACG/042/s.100/VOL.II tí ẹ̀dà rẹ̀ mííràn náà tún lọ sí ọ̀dọ̀ adari ti FAAN Rabiu Yadudu ati adari NAMA Fola Akinkuotu.

Lẹ́tà náà dari àwọn ilé iṣẹ́ tó n mójú tó ìgbòkè gbodò ọkọ̀ òfurufú (NCAA) àwọn àlámojútó ìrìnnà ojú òfurúfú (NAMA) àti awọn aláskosọ pápápkọ̀ òfúrufú (FAAN) láti má jẹ kí ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ ofurufú aládani yìí fò títí wọ́n yóò fi sàn gbogbo gbèsè tí wọ́n jẹ.

Nínú lẹ́tà náà ni wan ti kọ pé àwọn ti sáájú pé àwọn ti ọ̀rọ̀ kan lái fún wọ́n ni gbedeke inu osùn kẹjọ ọdún yìí láti sàn owó tí o tọ nígbà ti wọ́n gbé ọkọ̀ náà wọ́le sùgbọ́n títí di àsìkò yìí tí wọn ko ṣe ohun tí ó tọ́

Sáájú nígbà ti wọ́n kọ́kọ́ fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ́ iye ọkọ̀ ofurufú aládani tó jẹ́ mọ́kàndílọ́gọ́run ni o jẹ́ ti àwọn pásítọ̀ ńláńla ni Nàìjíríà, àwọn ọ̀gá àgbà Bánki tó fi mọ́ bánki kan ti o ni méji irú rẹ̀, àwọn ọ̀gá ilé epo rọ̀ọ̀bì wà lára wọn

Ní báyìí àwọn kan lára wọn tí ìjọba pé ti wọ́n ń fi ọkọ̀ ofúrúfu ti wọ́n gbé èrò, ni wọ́n ti an gbese wọn ti wọ́n si ti padà sí ẹnu iṣẹ́ sùgbọ́n àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́run tó ku kò yọjú debi ti wọ́n yóò gbé ìgbésẹ̀ láti se àtúnsọ́

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fi hàn, àwọn kan nínú àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́run náà ti kọ iwé ìfẹ̀honúhàn si ilé isẹ́ aṣọbodè pé àwọn ko le san owo orí lórí àwọn ọkọ̀ náà nítorí bi ẹni pe àwọn ya ni ti àwọn sì ń san owó díẹ̀díẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, ilé iṣẹ́ asọbọde náà ti da èsì pàdà pé ìwà jìbìtì ni wam hù áti fi àwọn iwé ayédèrú gbé àwọn ọkọ̀ òfururufú náà wọlé.