Cute Abiola: Ìyàwó Cute Abiola sọ̀rọ̀ lórí ìrirí ọkọ rẹ̀ ní àhámọ́ iléeṣẹ́ ọmogun orí omi

Cute Abiola ati Iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Cute Abiola

Kudirat Mosumola Aya adẹrinpoṣonu, Cute Abiola to ṣẹṣẹ gbominira kuro lakata ileeṣẹ ọmogun oju omi, ti sọ pe ọkọ oun ni lati ṣọra ṣe nibi ti ọrọ de bayii.

Kudirat Abiola sọ fun BBC Yoruba pe ko rọrrun fun oun ati ẹbi Abiola bi ọkọ ṣe wa lahamọ ileeṣẹ ologun fun bi oṣu kan.

''O dabi ẹni pe ki n gbe Cute Abiola mi ni nigba to pada sile lati ahamọ ileeṣẹ ọmogun oju omi.

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

Gbogbo ẹbi, ara ati ọrẹ lo fo soke fun ayọ nigba ti Cute Abiola pada de.

Ko rọrun fun mi rara lẹyin ti ọkọ mi ti lo ọjọ mejidinlọgbọn lakata awọn ologun.

Ileeṣẹ ologun sọ pe o ṣẹ, ṣugbọn fun emi o, ko tapa si ofin lọna kankan.

Tori awọn naa ka iwe ofin ileeṣẹ ologun yii a si ri pe iji ẹṣẹ ti wọn fun ọkọ mi lodi sofin.

Wọn tiẹ kọkọ fun wa ni anfaani lati maa ri Cute Abiola nigba to wa ni ahamọ ileeṣẹ ologun.

Igba ti emi ati iya ọkọ mi bẹrẹ si ni yi ara mọlẹ ni wọn to gba wa laaye lati le maa ri i ba sọrọ,'' iyawo Abiola lo sọ bẹẹ.

Lara ẹṣẹ ti wọn ka si Cute Abiola lẹsẹ ni pe ko gbe fọto alabaṣiṣẹ rẹto wa aṣọ ibi iṣẹ sori ayelujara, amọ o sọ pe irọ ni kawọn eeyan lọ wo oju opo rẹ.

Lẹẹkeji, wọn ni Cute Abiola gbe ibọn dani ninu fiimu Jennifer's diary.

Amọ o ni kii ṣe ibọn gidi pe "Props lasan ni, aṣọ ti wọn tun ni o wọ aṣọ Ọlọpaa, o ni irọ ni, Costume lasan ni koda o fẹẹ fara jọ aṣọ awọn ẹṣọ aabo.

Ni ọjọ Aje ọjọ kẹtala oṣu kejila ọdun 2021 ni wọn fun Cute Abiola ni ominira.