Nigeria Police 20% salary Increase: Wo àwọn orílẹ̀-èdè márùn ùn tí owó oṣù ọlọ́pàá wọn ju ti Nàìjíríà lọ

Aworan awọn ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orileede Naijiria ti kede afikun owo oṣu ida ogun ninu ida ọgọrun fawọn oṣiṣẹ ọlọpaa.

Ṣaaju asiko yi ni aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣeleri lati fikun owo wọn lasiko iwọde ENDSARS to waye lọdun to kọja.

Minisita fọrọ iṣẹ ọlọpaa, Muhammadu Dingyadi lo fi ọrọ yi to awọn akọroyin leti nile ijọba lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ lỌjọru.

O sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lati le mu ọkan ọlọpaa kuro nibi gbigba abẹtẹlẹ. Bẹẹ lo ni afikun yi yoo jẹ ki ibaṣepọ to mọranyin wa laarin wọn ati araalu.

Àkọlé fídíò, Araalu sọrọ lori afikun owo osu osisẹ lorilẹede Naijiria

Sisan afikun owo yi yoo bẹrẹ lati oṣu kini ọdun 2022.

Yatọ si afikun yi, ijọba lawọn yoo foju fo owo ori fawọn ọmọ iṣẹ nidi iṣẹ ọlọpaa. Iṣiro yiyọ owo yi ti bẹrẹ lati oṣu Kẹwa ọdun.

Lara nkan tawọn ajafẹtọ to ni ki wọn tu ikọ ọlọpaa SARS ka n beere fun ni afikun owo oṣu awọn ọlọpaa.

Àkọlé fídíò, Mariam Balogun kunlekunle to fi gboorọ jẹka laarin awọn akẹgbẹ rẹ

Owo oṣu ọlọpaa ni Naijiria wa lara awọn eyi to kere julọ lagbaye to si jẹ ipenija to n kọdii ki awọn ọlọpaa ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ.

Afiwe owo oṣu Naijiria si tawọn orileede mii

Iṣẹ to ṣe pataki lawọn ọlọpaa nibi kibi ti wọn ba wa lagbaye n ṣe.

Pataki julọ nibẹ ni didaabo bo ẹmi ati dukia araalu.

Ki iṣẹ wọn baa le lọ deede owo oṣu to peye ni ijọba gbọdọ san. A ṣe agbeyẹwo owo oṣu ọlọpaa lawọn orileede kan lafiwe eleyi ti awọn ti Naijiria n gba.

Ẹ wo iyatọ laarin wọn:

1. Canada

Aworan ọlọpaa Canada

Oríṣun àwòrán, Royal Canadian Mounted Police in Ontario

Awọn ọlọpaa Canada lo n gba owo julọ lagbaye. O kere tan wọn a maa san owo to le ni $100,000 fun wọn lọdun.

Idi towo wọn fi pọ ni pe bi wọn ba tun ṣe iṣẹ mi kun bii ki wọn maa sọ awọn eeyan lode tabi laaye akanṣe iṣẹ,ọtọ lowo eyiun.

Aworan ọlọpaa Canada

Oríṣun àwòrán, Canada

Koda bi wọn ba lọ jẹri nile ẹjọ, wọn a san owo''over-time'' fun wọn.

Ọlọpaa ti wọn ba ṣẹṣẹ gba lẹnu iṣẹ a maa gba to $50,000 lọdun

2. Switzerland

Awọn ọlọpaa Zurich lorileede yi a maa gba to $73,472 lọdun.

Ni iṣiro Naira lojumọ toni to mọ, owo yi to ₦30,353,487.36

Apapọ awọn ọlọpaa to wa lorileede yi ko ju 3,800 ti o ṣe pe iṣẹ yi nikan ni wọn n ṣe.

Aworan awọn ọlọpaa Zurich

Oríṣun àwòrán, Facebook/PolizeiZH

Ni ọdun 2015, iye agọ ọlọpaa ti wọn ni ko ju ọgọta lọ.

Iṣẹ wọn ko si ju ki wọn sọ agọ ọlọpaa, ki wọn maa sọ oju popo ati dida ọkọ.

Yatọ si eleyi, wn a tun maa ṣe iwadii iwa ọdaran wọn a si tun maa sọ oju omi nilẹ naa.

3. Orileede Amẹrika

Owo to kere julọ tawọn ọlpaa Amrika n gba ni $60,000 ṣugbọn lu ti wọn ba ti n ṣiṣẹ tabi iriri wọn lẹnu iṣẹ ni yoo tọka iye ti wọn maa gba.

Awọn ọlọpaa to wa ni New York, California ati New Jersey lo n gba owo julọ laarin akẹgbẹ wọn.

4. Ilẹ Gẹẹsi

Owo ti wọn fi n bẹrẹ pẹlu ọlọpaa to ṣẹṣẹ gbaṣẹ ni ilẹ Gẹẹsi wa laarin £19,400 si £23,000 lọdun

Aworan ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Facebook/metpoliceuk

Aworan ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Facebook/metpoliceuk

Amọ apapọ iye owo oṣu to kere julọ ni UK jẹ £31,000 ($38,000) lọdun eleyi to sunmọ ₦15,698,940.00

Afikun ni pe awọn ọlọpaa UK kii ṣiṣẹ ju wakati ogoji l laarin ọsẹ kan.

5. Australia

Ni Australia, owo tokere julọ ti ọlpaa n gba lọdun ni $42,000

Wakati ogoji ni wọn a maa fi ṣiṣẹ laarin ọsẹ amọ bi wọn ba ṣe alekun iṣẹ wọn maa n fun wn lowo si.

Elo wa ni ọlọpaa Naijiria n gba?

Aworan awọn ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force

Ni iṣiro ilẹ toni to mọ lai ti fi alekun si, iye owo ti o kere ju ti ọlọpaa Naijiria n gba ni $1,700 lọdun.

Taa ba ṣiro owo yi ni Naira a si maa jẹ nkan bi ₦702, 321.00

Bi a ba tun wa ge owo yi si iye owo ti wọn n gba lojumọ ko le ju bi $4 lọ to jẹ bi ₦1652.52

Nkan bi ọlọpaa 250,000 lo wa ni Naijiria.

Owo taa ṣiro yi jẹ iye owo ti wọn a maa san fun ọlọpaa to ba ṣẹṣẹ wọ iṣẹ.