Teen traffic robber in Lagos: Bí Ọlọpàá ṣe mú ọmọ ọdún 18 tó ń dúró sójú pópó ja olè

Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọmọ ọdun mejidinlogun kan to maa n lọ si oju popo lasiko ti awọn ọkọ n rin lati lu awọn eeyan ni jibiti ti bọ sọwọ ikọ Ọlọpaa asare-si-pajawiri (Raapid Response Squad) ti ipinlẹ Eko.

Ikọ RRS fi si oju opo wọn pe ọdọkunrin naa jẹwọ pe oun tun pada lọ si oju popo lati lọ ko owo jọ lati san gbese to jẹ lẹyin igba ti wọn tu u silẹ lẹwọn ni ọsẹ mẹrin sẹyin.

Afurasi adigunjale naa, Sodiq Abubakar ni wọn fi panpẹ ofin mu ni nkan bii ago mẹjọ alẹ ọjọ Ẹti to kọja ni agbegbe Ketu laipẹ asiko to lo ohun ija kan fi dẹru ba awakọ kan to si gba ẹgbẹrun meje naira lọwọ rẹ ninu sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Sodiq ṣalaye pe oun ya awọn owo kan lẹyin ti wọn tu oun silẹ lọgba ẹwọn lati fi ra ogun. O fi kun un pe lẹyin ti ẹni ti oun jẹ lowo ko fi oun lọrun silẹ loun ṣe ni koun lọ ja ole lati ko owo jọ fi san gbese.

Àkọlé fídíò, Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

"Emi ati ẹni ti a jọ n ṣe iṣẹ ole jija yii, Ahmadu to ti salọ bayii halẹ mọ onimọto pe a o fọ gilaasi ẹgbẹ rẹ bo ba kọ lati ko owo to wa lapo rẹ silẹ". O fi kun un pe ẹni naa ko ẹgbẹrun meje silẹ.

Nigba to n bbẹ fun aanu lo ṣalaye pe ọsẹ mẹrin naa ni wọn ṣẹṣẹ tu oun silẹ lahamọ RRS.

O ni oun pade Ahmadu lori afara Otedola ni Eko wọn si jọ pinu lati ja ole ninu sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ. Awọn ti wọn ja lole lo sare fi to ikọ RRS Eko to sunmọ agbegbe naa leti ti wọn si gba a mu nigbati Ahmadu ni tirẹ sa lọ.

Akọsilẹ nipa Sodiq ti ikọ RRS ni lọdọ wọn ṣafihan pe wọn ti mu u ni Ketu fun iwa ọdaran oju popo lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹfa ọdun 2021 ti wọn si dajọ ẹwọn oṣu mẹta fun un.

Bakan naa lọjọ Kọkandinlogun oṣu Kẹsan ọdun 2021, wn tun fi panpẹ ba mu u ni agbegbe Alapere fun iwa ole inu sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ amọ ti ikọ RRS gbe ọrọ rẹ lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Alapere bakan naa fun ijiya to ba tọ.

Nibayii wọn ti ni wọn yoo gbe e lọ si ile ẹjọ gẹgẹ bi aṣẹ Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu.