Timothy Adegoke: Ètò tí n lọ láti mú ọmọ Adedoyin tí ìròyìn sọ pé ó darí bí wọ́n ṣe sin òkú Timothy ní Hilton Hotel

EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àjọ EFCC ní àwọn ọmọ Naijiria yóò gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ribiribi tí òun n ṣe láìpẹ́ pẹlu bi wọn ṣe tun gun le titu aṣiri gomina kan.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, sọ pe gomina kan ti gba to ọgọta biliọnu Naira kuro ninu apo àsùnwọ̀n ipinlẹ rẹ laarin ọdún mẹfa to ti lo ni ipo.

Botilẹ je pe àjọ EFCC ko darukọ gomina naa tabi ipinlẹ rẹ, o ni aarin gbungbun Ariwa Naijiria lo ti wa.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pllú omíjé kíkorò ...'

Ninu iwe iroyin atigbadegba àjọ naa ni Ọga Agba wọn Abdulrasheed Bawa ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo gbọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ laipẹ.

O ni àjọ naa n ṣiṣẹ ribiribi labẹnu, paapaa lori igbogun ti jibiti ori ayelujara, iwa ibajẹ laarin awọn oloselu ati ileesẹ ijoba.

Eyi to ni gbogbo abajade àwọn iṣẹ́ akọni naa ni àwọn ọmọ Naijiria yoo gbọ nipa rẹ to ba to asiko to yẹ.

Ọgbẹni Bawa sọ pe isẹ kekere kọ ni ẹka iwadii tuntun ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ ninu àjọ EFCC n ṣe.