Guinea-Bissau 'coup attempt': Ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea Bissau, wo ohun tí a lè fìdíẹ̀ múlẹ̀ nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdìtẹ̀gbàjọba tó fìdí rẹmi ní Guinea-Bissau lọ - Ààrẹ Embaló
Ààrẹ Embaló ní ọ̀pọ̀ ènìyàn dágbére fáyé níbi ìdìtẹ̀gbàjọba tó fìdí rẹmi ní Guinea-Bissau
Ààrẹ Umaro Cissoko Embaló ti ní ìdìtẹ̀gbàjọba tó fìdí rẹmi ní orílẹ̀ èdè Guinea-Bissau ṣokùnfà kí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò.
- Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah Agboluaje, akẹ́kọ̀ọ́ tó kú sí Ukraine ní ọjọ́ kejì tó dé ibẹ̀
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
- Ọkọ mi tẹ́lẹ̀ àti Adekaz kò fi ìgbà kankan jẹ́ ọ̀rẹ́, kìí sẹ ọ̀rẹ́ ọkọ mi ni mo fẹ́ - Mercy Aigbe
- Ìjọba Tanzania yòó fi òfin gbé òbí tí ọmọ rẹ̀ bá sá nílé ẹ̀kọ́
- Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle
Kini Aarẹ Embalo kọkọ fi sita?
Ààrẹ Embaló ṣàlàyé pé àwọn ṣe ohun gbogbo tó wà ní ìkáwọ àwọn láti ri dájú pé ìdìgbàjọba náà kò wáyé bí ó ṣe ní àbùkù ní sí ètò ìjọba àwaarawa.
Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gún ni ìró ìbọn bẹ̀rẹ̀ sí ní dún ní ẹ̀gbẹ́ ilé Ààrẹ lásìkò tó ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ rẹ̀.
Ìròyìn ní àwọn ológun fi Ààrẹ àti àwọn Mínísítà rẹ̀ sí àhámọ́ nígbà tí àwọn kan yabo ilé Ààrẹ lásìkò tí Ààrẹ Embaló ń ṣèpàdé pẹ̀lú Mínísítà Nuno Gomes Nabiam.
Ẹ̀ṣọ́ aláàbò kan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun tó bá ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀ ní àwọn agbébọn náà pa ọlọ́pàá kan nígbà tí wọ́n dàbọn bolẹ̀ lásìkò tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ẹ̀bá ilé Ààrẹ.
Àwọn adarí ìwọ̀ oòrùn ẹkùn Adúláwọ̀ ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìdìtẹ̀gbàjọba tó ń wáyé tí wọ́n sì ní kí àwọn ológun padà sí bárékè.
















