Atiku Abubakar: Mi ò kọ Atiku Abubakar nítorí pé o fẹ́ ìyàwó mìíràn- Jennifer Douglas Abubakar

Atiku ati Jennifer

Oríṣun àwòrán, Others

Jennifer Douglas Abubakar, ọ̀kan lára àwọn ìyàwó ìgbákejì Ààrẹ orílẹ̀èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar ti tú pẹrẹpẹrẹ ọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣokùnfà ìtúká láàrín òun àti ọkọ rẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, Jennifer ní kìí ṣe nítorí Atiku fẹ́ ìyàwó tuntun ni òun ṣe fẹ́ kọ̀ọ́ tàbí nítorí ọ̀rọ̀ ogún.

Ó ṣàlàyé pé láti ọjọ́ 26, oṣù kẹfà, ọdún 2021 ni òun ti ń bèèrè fún ìtúká ìgbéyàwó àwọn lọ́wọ́ ọkọ òun.

Kíló ṣẹlẹ̀ gan an:

Jennifer ní ìdí tí òun fi ń bèèrè fún ìpínyá láàárín àwọn ni aáwọ̀ tó ń wáyé látàrí bí òun ṣe kọ̀ pé òun kò ní fi orílẹ̀ èdè United Kingdom sílẹ̀ àti àwọn aáwọ̀ tó ti máa ń wáyé láàárín àwọn fún ọjọ́ pípẹ́.

Atiku ati Jennifer

Oríṣun àwòrán, @Premium Times

Jennifer Iwenijiora Douglas Abubakar ní òun ti mọ̀ wí pé ó fẹ́ ìyàwó tipẹ́tipẹ́ bí kò tilẹ̀ sọ fun òun, ṣùgbọ́n òun mọ̀ pé mùsùlùmí ni ó sì ní àǹfàní láti fẹ́ ju ìyàwó kan lọ.

Ó sọ síwájú pé àwọn ọ̀rẹ́ Atiku gbìyànjú láti paná aáwọ̀ ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànjú já sí pàbó.

Tani Jennifer Iwenijora Douglas Abubakar ti wọn \n sọrọ rẹ lori ayelujara bayii?

Jennifer Iwenjiora Douglas-Abubakar ni iyawo kẹrin ti Abubakar Atiku fẹ sile.

O jẹ ọmọ bibi Onitsha ni ipinlẹ Anambra ni ẹkun South East ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Jennifer ṣiṣe pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan NTA ni sáà 1980s

Ko pẹ lo ko lọ si orilẹ-ede America nibi to ti kọ ẹkọ nipa imọ ofin ni Washington DC.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Jennifer jẹ akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro.

O bi ọmọ mẹta fun Atiku Abubakar ti oruko wọn n jẹ Abdulmalik, Zahra àti Faisal.

Àkọlé fídíò, Alhaji Shanko

Báwo lọ̀rọ̀ ogún ṣe jẹ́?

Nígbà ti Jennnifer ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ogún, ó ní Atiku gba ilé àwọn tó wà ní Asokoro ní Abuja tó ti ṣaájú fún òun lọ́wa òun.

"Nígbà tí mo bí pé níbo lèmi àti àwọn ọmọ mi yóò máa dé sí tí a bá wá Nàìjíríà, Atiku ní kí n lọ wá a nítorí òun ló fẹ́ kọ òun, mo sì kó jáde níbẹ̀."

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

"Ní báyìí, inú ewu ni èmi àti àwọn ọmọ mi wà nítorí àwọn ènìyàn Atiku kan ń dúnkokò mọ́ mi pé wọ́n fẹ́ gba ogún mí lọ́wọ́ mi, wọ́n ti pe àwọn ọ̀rẹ́ mi, ẹbí àti àwọn òṣìṣẹ́ mi."

"Fún ìdí èyí, mo ti kúró ní ilé iṣẹ́ mi, mo sì ti ta gbogbo àwọn ohun ìní mi, mo sì ti kó lọ sí ilẹ̀ òkèrè títí àláàfíà yóò fi jọba."

Jennifer ni pe nítorí à ti fọ orúkọ òun mọ́ ní òun ṣe fi àtẹ̀jáde náà síta.

Titi di asiko yii ni Abubakar Atiku ko sọ nkankan nipa ikọsilẹ naa.

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà