Oògùn olóró tó lé ní mílíọ̀nù kan la rí gbà lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ Onitsha sí Kano- Àjọ NDLEA

Oríṣun àwòrán, @NDLEA
Awọn osisẹ ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro ni Naijiria NDLEA lopin ọsẹ ti ribi gba oogun oloro orisi tawọn olubi n gbe lọ si Yauri lati Onitsha.
Ninu awọn oogun oloro yi la ti ri miliọnu kan aabọ tabilẹẹti Tramadol,Exol-5 ati Diazepam.
Ni ipinlẹ Edo ni wọn ti ri awọn oogun oloro yi gba taa si tun gbọ pe wọn gba tabilẹẹti 425,000n Diazepam mi ni Segemu ti wọn n gbe lọ si Kano.
Atẹjade kan lati ọwọ agbodegba NDLEA, Femi Babafemi sọ pe bẹẹ naa ni wọn tun ri ibọn ati ọta to le ni miliọnu kan gba lọwọ ogbologbo janduku ati olori awọn oloogun oloro kan ni ipinlẹ Plateau.
- Mi ò kọ Atiku Abubakar nítorí pé o fẹ́ ìyàwó mìíràn- Jennifer Douglas Abubakar
- China sinmi lórí yíyá Nàìjíríà lówó, èyí lè fà ìdádúró lórí iṣẹ́ rélùwé
- Ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea Bissau, wo ohun tí a lè fìdíẹ̀ múlẹ̀ nípa rẹ̀
- Jide Kosoko, Otunba Dodoede n selédè lẹ́yìn Tafa Oloyede tó kú
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó ń fa shisha l'Ogun ti padà sílé ẹ̀kọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ lọ rọ́kùn ńlé
Kini NDLEA tun ri gba?
Wọn fi kun un pe awọn tun tun ribi gba awọn oogun oloro to le ni ọgọrun kilo gbakaakiri awọn ipinlẹ meje lọsẹ to kọja.
Lọjọ Kẹ́rinla, osu Kini ni awọn osisẹ ajọ NDLEA sọ pe awọn ribi da ọkọ akẹru nla kan to n lọ si Yauri lati Onitsha.
Lẹyin ayẹwo finifini wọn sọ pe awọn ri awọn oogun oloro tawọn ọlọkọ naa gbe pamọ sabẹ ẹru ti wọn lawọn ko.
Awakọ naa Bashir Lawal to fi mọ awọn meji mii Abubakar Sani ati Ali Abubakar ti wa lọdọ awọn agbofinro ti wọn si ti gba akoso awọn oogun oloro ti wọn gba ni Kano lọwọ Saidu Yahya ẹni ọdun mọ́kanlelọgbọn.
Bakan naa ọwọ palaba awọn fayawọ oogun oloro kan to fẹ gba papakọ ofurufu Murtala Muhammed gbe igbo ti wọn di sinu ike ti segi.
Awọn osisẹ ajọ NDLEA gba awọn ati awọn miran ti wọn fẹ gbe igbo lọ si orileede Amẹrika gba inu baalu mu ti wọn si ti wa ni atimọle.
NDLEA mú òni fayawọ́ oògùn olóró ní Kano,Onitsha àti Portharcourt, Wò nkán tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wọn
- Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah Agboluaje, akẹ́kọ̀ọ́ tó kú sí Ukraine ní ọjọ́ kejì tó dé ibẹ̀
- Ajagbe Toriola Oyewo ògbóǹtarìgì agbẹjọ́rò SAN ti jáde láyé lẹni ọdún mọ́kànlélàádọ̀rún ùn
- Tí òògùn owó bá wà nínú Ifa ni, n kò bá ti kọ́ ilé ńlá fún ara mi- Babaláwo
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó ń fa shisha l'Ogun ti padà sílé ẹ̀kọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ lọ rọ́kùn ńlé
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
















