Dominic Adigezi àti ọmọ rẹ̀ mẹ́ta kú sínú oko ní Abuja, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, @NPF
Ọkùnrin kan àti àwọn ọmọ mẹ́rin ni wọ́n bá òkú rẹ̀ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta nínú oko nǹkan ọ̀sìn ní olú ìlú orílẹ̀ èdè wa, Abuja.
Àjọ ọlọ́pàá ṣàlàyé pé ní ìjọba ìbílẹ̀ Abaji, Abuja Oko náà wà.
Orúkọ ọkùnrin náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọ ọlọ́pàá ti fi síta ni Dominic Adigezi ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, Victoria Adigezi, Peter Adigezi, ọmọ ọdun mẹ́ta àti Judith Adigezi, ọmọ oṣù mẹ́ta.
- Agbára ṣì wà lọ́wọ́ Boris Johnson bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ n fi iṣẹ́ sílẹ̀
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́
- Wọ́n ti ri ẹni mẹ́wàá tó di àwátì nínú oko tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Abamẹ́ta tó kọjá ní Ondo
- Òògùn ìbílẹ̀ nílò ìrànwọ́ owó láti gbèrú síi, àjọ NAFDAC ké gbàjarè
- Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ ilẹ̀ America fi sún ọjọ́ ìdájọ́ Hushpuppi síwájú
- ''Àwa ẹgbẹ́ Agbekoya ṣetán láti tú Sunday Igboho sílẹ̀ lẹ́wọ̀n pẹ̀lú agbára àwọn àgba''
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ì tíì sí àrídájú ohun tó ṣokùnfà ikú wọn ní pàtó, ìyàwó ọkùnrin náà, Laraba Adigezi ṣì ń mí ṣùgbọ́n tó wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ ka ọ̀run.
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá FCT, Josephine Adeh ní ìyàwó náà ti wà ní ilé ìwòsàn Abaji Comprehensive Health Care Centre fún ìtọ́jú.
Kini Olopaa sọ bayii?
Adeh ní ọjọ́ Rú ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni baálẹ̀ ìlú Nasarawa Iggon Abaji pe àwọn pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn yóò fi dé ibẹ̀ Laraba nìkan ni àwọn bá ẹ̀mí lọ́rùn rẹ̀.
Bákan náà ló ní àwọn ti gbé àwọn òkú náà lọ sí yàrá ìgbóòkú sí ní ilé ìwòsàn tí Jẹ́nẹ́rà Abaji.
Oga ọlọpaa naa ni ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti mọ okùnfà ikú wọn.
















