Ayede Ogbese Kidnap: Wọ́n ti ri ẹni mẹ́wàá tó di àwátì nínú oko tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ní Ondo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọ́n ti ri ẹni mẹ́wàá tó di àwátì nínú okó tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ní Ondo
Saaju ni eeyan mẹ́wàá ti dàwátì nigba ti wọn lọ sinu oko wọn ni Ayede Ogbese nijọba ibilẹ Ariwa Akure nipinlẹ Ondo.
Awọn agbebọn kan ni wọn ni wọn yabo oko ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Femi Alawiye ni agbegbe Ayede Ogbese.
Won ni niṣe ni ọkunrin agbẹ naa, Femi Alawiye gba ipe kan pe oko rẹ n jona ni o ba sare gba oko lọ pẹlu diẹ ninu awọn oṣiṣẹ rẹ laimọ pe panpẹ ni awọn ajinigbe ti dẹ silẹ lati fi mu u.
- Inú wa kò dùn bí ó ṣe sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, lọ kọ́ síi nípa ọ̀rọ̀ tútù gẹ́gẹ́ bíi 'Ambassador'- Oluwafemiloye
- Ọ̀gá àgbà NSCDC dá àwọn ẹ̀ṣọ́ àjọ náà tó wà pẹ̀lú Shina Peller padà
- A kò fi ẹbí Timothy sílẹ̀, à ń gbiyànjú pé kí wọ́n dá ẹjọ́ náà padà sí Osun dípò Abuja ni- Agbẹjọ́rò Adekilekun
- Ìjọba Kano fẹ̀sùn oníkókó márùn ún kan àwọn afurasí tó pa ọmọ ọdún márùn ún Hanifa
- Ọdaràn làwọn tó ń pè fún ìdìbò dípò 'Restructuring' tí a n béèrè- Iba Gani Adams OPC
- Àwọn agbébọn pa ọgọ́ta èèyàn ní ibùdó ìfiniwọ̀ ní DR Congo
Kini o ti ṣẹlẹ lati igba naa?
Lọjọ Abameta, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kinni ni iṣẹlẹ yii waye ni ipinle Ondo.
Wọn ni itara ọrọ aje lo jẹ ki Femi Alawiye fi sare lo sibe to si pada di ogun fun awọn mẹwẹẹwa.
BBC fidie mule pe won ti pada ri ominira gba bayii kuro lọwọ awọn ajinigbe naa.
Alukoro ajọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo lo fidihe mulẹ fun BBC
Oga ọlọpaa Odunlami naa ni oun ko mo boya wọn san owo itanran tabi bẹẹkọ nitori pe ileeṣẹ ọlọpaa ko gbọ ohun to jọ owo itanran ninu orọ naa rara.
Awọn eeyan mẹwaanaa si ti pada si ile wọn bayii















