Boris Joihnson: Agbára ṣì wà lọ́wọ́ Boris Johnson bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ n fi iṣẹ́ sílẹ̀

Boris Johnson

Oríṣun àwòrán, NO 10 DOWNING STREET

Agbara ko tii bọ lọwọ olootu ijọba orilẹ-ede United Kingdom, Boris Johnson, botilẹ jẹ pe diẹ lara awọn amugbalẹgbẹ rẹ kọwe fi isẹ silẹ lọjọ Ẹti.

Agbẹnusọ fun Ọgbẹni Johnson sọ pe awọn ko reti iwe ifiṣẹ silẹ kankan mọ.

Ṣugbọn ṣa, ọmọ ile aṣofin kan tun ti kọwe pe oun ko ni igbagbọ ninu Olootu ijọba naa.

Aṣofin naa, Aaron Bell sọ lori Twitter pe iwa afojudi ni bi Ọgbẹni Johnson ṣe ṣe ayẹyẹ lasiko isede Coronavirus, ati iha to kọ si ero araalu lori iwa to hu.

Aṣofin mẹtadinlogun lo ti kọwe pe awọn ko ni igbagbọ ninu rẹ mọ. Amọ awọn mẹrinlelọgọta ni wọn nilo, ki wọn o to mọ boya wọn o yọ Johnson nipo.

Ileeṣẹ ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii ayẹyẹ mejila ọhun lati mọ olootu ijọba ati awọn oṣiṣẹ ọfiisi rẹ ṣe jẹbi to.

Ṣaaju ni agbẹnusọ rẹ sọ fun ileeṣẹ iroyin Rueters pe awọn amugbalẹgbẹ rẹ mẹta to fi isẹ silẹ ni Ọjọbọ wo awokọṣe ara wọn ni.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Ṣugbọn bi olori ẹka to n mojuto igbesẹ àtò ilu, Munira Mirza ati oludamọran, Elena Narozanski naa ṣe kọwe fi isẹ silẹ jẹ iyalẹnu.

Ireti ọpọlọpọ ọmọ orilẹ-ede naa ati awọn aṣofin ni pe Boris Johnson paapaa yoo fi ipo rẹ silẹ.

Amọ ninu ọrọ to ba awọn oṣiṣẹ rẹ sọ lọjọ Ẹti, Johnson sọ pe "akoko idojukọ to lagbara re e . Ṣugbọn o rọ wọn pe ki wọn o sọkan akin, nitori pe ko si ibi ti ayipada ko ti le waye.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere