Guinea-Bissau :Ààrẹ Umaro Sissoko sọ pé àwọn òní fàyàwọ́ oògùn olóró ló fẹ́ gba ìjọba mọ́ òun lọ́wọ́

Sọja to n le araalu

Oríṣun àwòrán, AFP

Aarẹ orile-ede Guinea-Bissau sọ pe awọn to gbiyanju lati ja ijọba gba lọwọ oun ni ọsẹ to kọja, ti ṣẹwọn ri nilẹ America fun ẹ̀sùn ṣíṣe fayawọ oogun oloro.

Umaro Sissoko Embaló sọ pe ọgagun ori omi nigba kan ri, ati amugbalẹgbẹ rẹ meji lo fẹ ẹ gbiyanju lati pa oun, olootu ijọba, ati awọn lọgalọga lẹ́nu isẹ ijọba.

O ni oun ri meji lara awọn ọkunrin naa nile ijọba lasiko ìdìtẹ̀gbàjọba to foríṣánpọ́n ọhun.

Inu ipade igbimọ alasẹ ni Aarẹ Embaló wa nigba ti awọn agbebọn ya wọ inu ọgba ile ijọba.

Eeyan mọkanla ni wọn pa, pupọ ninu wọn lo si jẹ òṣìṣẹ́ alaabo.

Orile-ede Guinea-Bissau jẹ ibi gboogi ti awọn oni fayawọ oogun oloro n gba sọ dá si South America ati Yúróòpù.

Lara ileri ti Aarẹ Embaló si ṣe fun araalu ni pe oun yoo fi opin si iṣẹ awọn oni fayawọ.

Ìdìtẹ̀gbàjọba bii mẹrin lo ti waye nilẹ Africa laarin ọdun meji.

Eyi si ti n kọ ajọ ECOWAS lominu pe nkan to n sẹlẹ lewu fun ilẹ̀ naa.

Nibi ipade kan ti wọn ṣe n'ilu Accra lorile-ede Ghana lọsẹ to kọjá, Aarẹ Nana Akufo-Addo to jẹ alaga ajọ naa sọ pe asiko ti to fun gbogbo olori orile-ede ni Iwọ oorun Africa, lati fọwọsowọpọ gbogun ti iwa ìdìtẹ̀gbàjọba.

Ẹ̀mí mọ́kànlá ló sọnù sí ìdìtẹ̀gbàjọba tó foríṣánpọ́n ní Guinea-Bissau

Ijọba ni Guinea-Bissau sọ pe eyan mọkanla lo ku lasiko iditẹgbajọba to forisanpọn ni orilẹ-ede naa lọjọ Iṣẹgun.

Awọn ọkunrin agbebọn ti ẹnikẹni ko tii mọ lo gbiyanju lati gbajọba lọwọ Aarẹ Umaro Sissoco Embaló.

Ijọba orilẹ-ede naa sọ pe ati sọja ati araalu lo ku.

Iwadii si ti bẹrẹ lati mọ awọn agbebọn to ṣe iṣẹ naa.

Lati ọjọ Iṣẹgun si ni àwọn ọmọ ogun ti n lọ kaakiri awọn adugbo to wa ni ilu to jẹ olu ilu.

Àwọn banki ati ile itaja ṣẹ̀ṣẹ̀ n pada si ẹnu isẹ wọn ni bayii. Sugbọn, eero perete lo n jade wa lati ra ọjà.

Àwọn adugbo to wa nitosi ile ijọba nibi ti iditẹgbajọba ọhun ti waye

Ibi gboogi ni Guinea-Bissau jẹ fun fayawọ egboogi oloro laarin ilẹ Latin America ati Yúróòpù.

Eyi si lo mu ki ọpọ eeyan gbagbọ pe isẹ ọwọ awọn olokoowo egboogi oloro ni iditẹgbajọba naa.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Bawo ni iditẹgbajọba naa ṣe waye?

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kinni, oṣù Keji, ọdun 2022, ni iro ìbọn deede bẹ̀rẹ̀ si ni n dun nile ìjọba, lasiko ti Aarẹ Sisocco Embaló n ṣe ipade igbimọ alasẹ.

Osisẹ alaabo kan sọ fun BBC pe awọn agbebọn naa ti ko wọ aṣọ ologun da ibọn bolẹ, ti wọn si pa ọlọpaa kan.

Àkọlé fídíò, Recycle Tyres: Wo bí wọ́n ṣe fi àlòkù táyà ṣe bàtà, ẹní onírọ́bà, táìsì àtí ẹ̀ṣọ́ ilé míì

Kini Aarẹ Guinea Bissau sọ si iṣẹlẹ naa?

Aarẹ Umaro Sissoco Embaló sọ pe awọn agbebọn naa gbiyanju lati pa oun ati gbogbo ọmọ igbimọ Aláṣẹ oun sinu ile ijọba.

O ni ori lo ko oun yọ lọwọ iditẹgbajọba to fẹẹ waye lasiko ti awọn osisẹ alaabo ati awọn agbebọn koju ara wọn fun wakati marun-un.

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Mọ sii nipa itan Guinea Bissau:

Orile-ede Guinea-Bissau jẹ ọkan lara àwọn to talika julọ ni agbaye, botilẹ jẹ pe ko ni ju miliọnu meji eeyan lọ

Igba mẹsan ni iditẹgbajọba ti waye nibẹ laarin ọdun 1980 si asiko yii.

Àkọlé fídíò, Reminisce: Àwọn ọ̀dọ́ ló mọ ìtumọ̀ orin 'Problem'

O dabi pe iditẹgbajọba ti n pada si Iwọ oorun ati Aarin gbungbun Afrika.

Laarin ọdun meji, àwọn ológun ti gba ijọba ni orile-ede Mali, Chad, Burkina Faso ati ni Sudan.