Oluwo: Mo fẹ́ kí gbogbo ọmọ Nàíjíríà gbà mí lórí ìyà tí Oluwo fi jẹ mi, ni mó ṣe pe ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Oluwo
Agbowu tilu Ọgbaagba, Ọba Dikrullahi Akinrọpo ti salaye lori idi to fi gbe Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi lọ sile ẹjọ lori ija to wa laarin wọn, lẹyin ti igbimọ lọba lọba ipinlẹ Ọsun ti dasi aawọ naa.
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Agbowu ni igbesẹ ti igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọsun gbe lori ọrọ naa, eyi to ni ki Oluwo lọ rọọkun nile na fun osu mẹfa ko tu irun kankan lara rẹ, tabi jẹ ko kabamọ nina to na oun.
- Ìgbà mẹ́rin tí ọ̀rọ̀ Oluwo dá awuyewuye sílẹ̀
- Ìjọba Ọṣun ti dásí ìjà láàrin Oluwo àti Agbowu
- Oluwo yí ìpinnu padà,Telu lóun yóò tẹlé àṣẹ lọ rọọ́kún nílé ṣùgbọ́n...
- Ìjọba Ọ́ṣun, Oluwo kò yẹ lẹ́ni tó leè darí ìlú, ẹ bá wa le kúrò lórí ìtẹ́ - Olú ti Ilé-Ogbó
- Gbogbo ẹ̀yin ọ̀ba abẹ́ mi, tí ẹ̀ ń ta ilẹ̀ ìlú, ẹ kò ní fara re lọ - Oluwo
"Se to ba jẹ ọgọrun ọdun ni igbimọ lọbalọba to tun jiroro lori ọrọ rẹ, se igba yẹ ni maa to sẹsẹ lọ sile ẹjọ, ofin kan si wa, eyi to ni to ba fi lee kọja asiko to yẹ ki n to pe ẹjọ, wọn yoo ni mo ti sun gbagbe ẹtọ mi."

Oríṣun àwòrán, Agbowu
Ọba Akinrọpo ni, se ni, Oluwo tun n sọ kaakiri pe igbesẹ ti awọn lọbalọba gbe naa ko kan oun tori oun si n jọba lọ ni, ti Oluwo ko si gba alaafia laaye lori aawọ naa, oun ko si lee gba ko fi iya jẹ oun gbe.
"Ẹni ti iya ba jẹ ko ni dakẹ, mo ti sọ funle ẹjọ pe ko se ẹtọ ati igbesẹ to daa lori iya ti Oluwo fi jẹ mi, amọ to pada sọ pe ko si ija kankan laarin wa. Ti eeyan ba si dakẹ, tara rẹ yoo ba dakẹ ni, mo si fẹ ki gbogbo ọmọ Naijiria gba mi lori iya to fi jẹ mi."
"Mo ti gbe lọ sile ẹjọ, mo si fẹ ko san owo ti mo n beere lọwọ rẹ, tii se miliọnu lọna ọgọrun naira, lẹyin naa, ohun to ba wu ileẹjọ ko se fun. Boya ko yẹ lẹni to n joko sori itẹ yẹn, ki wọn sọ, tori lati igba to ti jọba, ẹjọ rẹ to wa nile ẹjọ kii se ọna mẹrin mọ, ti temi yii tun wa pẹlu rẹ. Se iru eeyan bayi laa mọ ba gbe, ta maa wo pe ọba ree, ti ko si isinmi fun ẹni kankan ta jọ wa ladugbo."
Nigba taa beere pe se o tun seese ki wọn pada maa se papọ lẹyin ti wọn ba tileẹjọ de, Agbowu ni laelae awọn ko lee se ọrẹ mọ.
O ni nitori Oluwo jinna si oun, koda ko si ninu abile kẹta si oun, ti ko si roo wo pe agbalagba ni oun, ko to maa gba iru oun leti, kii se epe, oun ko lee de aafin Oluwo mọ, yoo si dara ki oun fi ọwọ mu aafin rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Omijé bọ́ lójú mi nígbà tí mo rí olóògbé Pa Kasumu gbẹ̀yìn - Lere Paimo
- A dúpẹ́ o! Lẹ́yìn àyẹ̀wò, kò sí alárùn Coronavirus ní Nàíjíríà, sáká lara wa dá - Mínísítà
- "Àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn bí mo ṣe yípadà láti obìnrin sí ọkùnrin, ń kò bá tí ṣe bẹ́ẹ̀"
- Kaduna tún gbàlejò ìkọlù àwọn agbébọn, àádọ́ta èèyàn míì rọ̀run ọ̀sán gangan
- Gómìnà Oyetọla tí yi ìlànà ètò ẹ̀kọ Rauf Aregbesola pada
- Obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ẹrú ní Oman tó bá fẹ́ òmìnira, yóò bá ọ̀gá rẹ̀ ṣùn - obìnrin méjì tó ti oko ẹrú dé
Nigba to n sọrọ lori ohun ti Oluwo lee se, ti oun yoo fi gbe ẹjọ naa kuro nileẹjọ, tawọn yoo si yanju rẹ nitubi n nubi, Ọba Akinrọpo ni Oluwo gbọdọ lọ pada tun oun se nibi gbogbo to ti ba orukọ oun jẹ de, paapa lọdọ awọn ileesẹ iroyin gbogbo, nibi to ti n pe oun ni baalẹ lasan-lasan, pe ko si ohun ti oun lee se.
"Oluwo yoo lọ pada sọ fun gbogbo agbaye to gbọ nigba to fiya jẹ mi pe asise gbaa ni oun se, oun si tuuba."
Agbowu wa fi idaniloju han pe awọn ẹri to daju wa nilẹ lati fi gbe ẹjọ oun nidi nitori ọpọ awọn ọba to wa nibẹ nigba to n na oun lo setan lati jẹri gbe oun, bẹẹ si ni kọmisana fun ọrọ oye jijẹ nipinlẹ Ọsun ati akẹẹgbẹ rẹ fọrọ ilẹ naa wa nibẹ pẹlu alaga ijọba ibilẹ Iwo.
"Koda, bi a ko ba fi alukurani bura, ka fi bibeli bura, amọ̀ ki awa ati ọ̀ga ọlọpa to ni Oluwo ko na mi, ka jọ̀ da ibọ̀n kọ̀ja, ko wa sọ̀ pe ko ri bẹẹ Bi ọga ọlọpa fẹ ni oun ko sọrọ tori ọrọ ijọba ki wọn jẹ ka da ibọn kọ ja, emi nikan kuku kọ ni mo wa nibẹ, awa ọba to wa nibẹ pọ, ẹlẹri mi si ni wọn."
BBC Yoruba tun kan si Oluwo lori ẹrọ ibaraẹni sọrọ rẹ lati mọ iha to kọ si bi Agbowu se gbe lọ sile ẹjọ, amọ ko gbe ipe wa, nigba ta si fi atẹjisẹ ransẹ si lori foonu, Oluwo ni oun ko ni esi kankan lati sọ lori ọrọ naa.
Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ! Agbowu pe Oluwo l'ẹ́jọ̀, ó ń bèèrè ₦100m owó gbà má bínú

Oríṣun àwòrán, Ọba Dikrulahi Ọlaleke Akinrọpo, Ọlabiran Kẹta.
Saaju la ti kede fun yin pe Agbowu ti ilu Ọgbaagba, Oba Dhikirullahi Akinropo ti wọ Oluwo ti Iwo, ba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni, lọ si iwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun, to si n beere fun owo gba, ma binu tii se ọgọrun miliọnu Naira fun bi Oluwo ṣe fi iya jẹ ẹ.
Ninu iwe ipẹjọ naa ti wọn kọ l'ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2020, lati ọwọ agbẹjọro rẹ, Soji Oyetayo, ni wọn ti kọ ọ pe, Agbowu tun n beere pe ki ile ẹjọ fi ofin de Oluwo ati awọn iranṣẹ tabi aṣoju rẹ, lati mase tun fi iya jẹ Agbowu mọ.
Bakan naa ni Agbowu tun n fẹ ki ile ẹjọ ni ki Oluwo fun oun ni miliọnu kan Naira gẹgẹ bi owo ti oun fi pe lẹjọ.
Agbowu fi ẹsun kan Oluwo ninu iwe ipẹjọ naa pe, o kọlu oun ni ọfiisi Igbakeji Ọga ọlọpaa, niwaju awọn ọba miran, ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Osun, to si fi egbo si oun lara.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Telu1
O ni wọn pada tọju oun ni ileewosan ijọba to wa ni Asubiaro nilu Osogbo.
Awọn ọba mẹfa miran lati ijọba ibilẹ mẹta ti wọn sọ pe ọrọ naa ṣoju awọn naa, kọ ọrọ ẹri wọn lati ṣatilẹyin fun ẹsun ti Agbowu fi kan Oluwo.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2020, ni iroyin jade sita pe, Oluwo ti Iwo na Agbowu ti Ogbaagba nibi ipade alaafia ti Igbakeji Ọga ọlọpaa pe, lati yanju wahala to n waye laarin awọn ọba mẹjọ kan, ati Oluwo.
Ẹsun ti Oluwo fi kan awọn ọba naa ni pe, wọn n ta ilẹ ilu wọn lọna ti ko ba ofin mu, sugbọn awọn ọba naa sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ.
Lẹyin ti Oluwo fi iya jẹ Agbowu tan, ni igbimọ lọba-lọba ipinlẹ Osun paṣẹ pe ki Oluwo lọ ọ rọkun nile fun oṣu mẹfa.















