Coronavirus: Mínísítà ní àwọn èèyàn tí wọ́n kó pamọ́ ní Eko àti Plateau kò ní àrùn náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita fun eto ilera, Osagie Ehanire ti sọ pe, awọn ọmọ orilẹ-ede China mẹrin ti wọn ko pamọ fun itọju arun Coronavirus nipinlẹ Plateau, ko ni arun naa.
Osagie sọ fun awọn akọroyin nibi ipade ita gbangba kan to waye n ilu Abuja pe, ko si ẹnikẹni lara awọn eeyan naa to ni arun ọhun, lẹyin ti wọn ṣayẹwo wọn ni ileeṣẹ ijọba to n ṣetọju arun, NCDC.
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Plateau ti kede pe, o ṣeṣe ki awọn eeyan naa ni arun Coronavirus lẹyin ti wọn de si Naijiiria lati China, to si fi wọn si apamọ fun ayẹwo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn bí mo ṣe yípadà láti obìnrin sí ọkùnrin, ń kò bá tí ṣe bẹ́ẹ̀"
- Kaduna tún gbàlejò ìkọlù àwọn agbébọn, àádọ́ta èèyàn míì rọ̀run ọ̀sán gangan
- Obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ẹrú ní Oman tó bá fẹ́ òmìnira, yóò bá ọ̀gá rẹ̀ ṣùn - obìnrin méjì tó ti oko ẹrú dé
- Ọ́lọ́pàá bá aṣọ, bàtà àti fóónù ọkùnrin tó dàwátì nílé Pásítọ̀ etí òkun l‘Eko
- Ẹ fi ọkàn balẹ̀ lórí àrùn Coronavirus, à ń ṣa ìpa wa láti dènà ìtànkálẹ̀ rẹ̀ - Buhari
- Ẹ́ fún ọmọ Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro dípò kẹ rán Boko Haram tó ronúpìwàdà lọ kàwé lókè òkun - Serap
O tẹsiwaju pe, ipinlẹ naa ti fi awọn ọmọ orilẹ-ede China ọhun sabẹ itọju, nibi ti awọn eleto ilera yoo ti bojuto wọn fun ọjọ mẹrinla fun ayẹwo siwaju sii.

Ẹwẹ, Osagie ni ko tii si ẹni kankan to tii lugbadi Coronavirus ninu gbogbo awọn eeyan to ṣabapade okunrin ọmọ orilẹ-ede Italy, to ko arun ọhun wọ Naijiria nilu Eko.
O ni "Gbogbo awọn eeyan to pade ẹni naa ni ipinlẹ Eko ati Ogun ni wọn ti n gba itọju lọwọ, ṣugbọn ko tii si ẹnikẹni lara awọn eeyan naa to tii lugbadi arun naa."

Oríṣun àwòrán, @InsideOjodu
Minisita ọhun wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati mase bẹru lakoko yii, nitori ijọba apapọ n ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri pe arun naa ko tan kalẹ ju bo ṣe yẹ lọ.
Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijira lati mu imọtoto ni pataki, lati maa fọ ọwọ wọn pẹlu ọsẹ, ati lati jina rere ni nnkan bii iwọn eṣẹ bata marun, si ẹni to ba nsin tabi wukọ layika wọn.
Osagie pari ọrọ rẹ pe, ki awọn eeyan maa bo imu ati ẹnu wọn pẹlu igbọnwọ, ki wọn si rọ awọn eeyan to ba sun mọ wọn lati ṣe bẹẹ pẹlu.













