Venus Williams virginity: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Venus Williams kò tíì mọ ọkùnrin lọ́mọ ọdún 41?

Oríṣun àwòrán, Venus Williams
Ọrọ nla ni ọrọ jija abale ọdọbinrin laye ọjọun.
Nitori naa, ọpọ obinrin ni wọn kii ti ni ibalopọ ri pẹlu ọkunrin ki wọn to lọ si ile ọkọ.
Iyi nla lo si maa n jẹ fun wọn ati ẹbi wọn ti ọkọ wọn ba le ba wọn nile lasiko orun akọkọ ti wọn ba jọ sun.
- ''A kò ní dẹ́kun ìfẹ̀hònúhàn àyàfi tí ìjọba àtàwọn aláṣẹ FUTA bá gbé ìgbésẹ̀ lórí ètò àbò àwa akẹ́kọ̀ọ́''
- Ki gan an ló mú kí awuyewuye pọ̀ lórí ìkéde èròngbà Tinubu láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà?
- Èmi ò sọ̀rọ̀ sí Bobrisky lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní Benin, irọ́ ni ìwé ìròyìn tó gbé e pa mọ́ mi- Femi Branch
- Wo ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí ayélujára sọ di ìlúmọ̀ọ́ká
- Láìṣẹ̀, láìrò, Arákùnrin ẹni ọdún 43 fi ipá ba ìyá arúgbó ẹni ọdún 80 lo pọ
- Gómìnà Wike dá rúgúdù sílẹ̀ láàárín ọlọ́pàá, Sífú dìfẹǹsì lórí ẹsùn fàyàwọ́ epo rọ̀bì
- Mọ̀ síi nípa àǹfàní tí lílo Àlùbọ́sà Aáyù lè fún ìlera ìwọ àti ẹbí rẹ
Bakan naa, itiju nla lawọn ti ọkọ wọn ko ba bawọn nile maa n ba bọ nibẹ atawọn ẹbi wọn.
Amọ, gbogbo nkan ti yatọ laye ode oni, ọpọ ọmọdebinrin lo ti n mọ ọkunrin ki wọn to mura lati lọ si ile ọkọ rara.
Awọn obinrin kan si tun wa laye ode oni ti wọn ko tii mọ ọkunrin bo tilẹ jẹ pe ọjọ ori wọn ko kere.
Iru obinrin bẹẹ ni agbabọọlu tẹniisi ọmọ orilẹede Amẹrika, Venus Williams eleyii ti iroyin sọ pe ko tii mọ ọkunrin di akoko yii.

Oríṣun àwòrán, Venus Williams
Iroyin ti a gbọ ni pe, Venus ko tii mọ ọkunrin bo tilẹ jẹ pe o ti pe ọmọ ọdun mọkanlelogoji bayii.
Koda, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa ọdun 2022 yii ni Venus yoo pe ọdun mejilelelogoji.
Sibẹ naa, ohun ti a gbọ ni pe ko tii ni nibalopọ pẹlu ọkunrin kankan ri lati igba to ti gbọnju.
Venus ti maa n sọ fawọn akọroyin pe oun ko ni igbagbọ ninu ibalopọ pẹlu ọkunrin afẹsọna ṣaaju igbeyawo.












