Jaigbade Alao, àgbà ọ̀jẹ̀ olórin dadakuàdà tó fiṣẹ́ orin sílẹ̀ ní Ilorin lẹ́ni ọgọ́fà ọdún

Jaigbade Alao Dadakuada

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Jaigbade Alao Dadakuada

Bi eeyan ba maa n fi ọkan ba orin dadakuada bọ ko ni jẹ ajoji si ti wọn ba darukọ Jaigbade Alao.

Sawawu kan naa ni Jaigbade wa pẹlu awọn olorin Dadakuada mii bi Odolaye Aremu, Aremu Ose, Iyabo Baluu, Omoeke Amao ati Iya Tamiwo.

Amọ ninu gbogbo wọn, ko si ẹni ti wọn da lọla pẹlu oye Oba Orin bi ti Jaigbade Alao.

Tani Jaigbade Alao?

Jaigbade Alao taa bi ni ilu Ilorin ti kede pe oun ti setan bayi lati fi isẹ orin kikọ silẹ lẹyin ọpọ ọdun.

O kede ọrọ yi ni aafin Oba ilu Ilorin, Emir Ibrahim Zulu Gambari laipẹ yi.

Àkọlé fídíò, Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Bi ẹ ba salabapade fọnran fidio ibi to ti lọ kan saara si Emir, Jaigbade Alao sọ pe oun n palẹmọ ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọfa ọdun oun ati pe asiko to lati fa isẹ orin le ọmọ oun Muhammad Jamiu lọwọ.

Ọtọ ni tọlu ọtọ ni tọlu wo, ninu awọn olorin ibilẹ Dadakuada, Alhaji Aminullahi Jaigbade Alao tan bi osupa to si da yatọ kedere.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà mẹẹ̀dógún ni mo ti ṣẹ́ oyún'

Akọsilẹ wa pe o ti n ba isẹ orin bọ, ọjọ ti pẹ.

Ninu awọn Emir Ilorin, o kere tan,mẹrin ninu wọn ni Jaigbade kọrin fun bẹrẹ lati igba Emir Abdulkadir Suhaib Bawa (1920 -1959) titi to fi kan Emir toni Emir Ibrahim Zulukarnaini Gambari.

Àkọlé fídíò, Jejere

Dadakuada, iru orin wo ni à n pe bẹẹ?

Ilu Ilorin ni Dadakuada ti gbilẹ daadaa, ti o si fidi mulẹ gẹgẹ bi orin ibilẹ nibẹ.

Tonile talejo to nifẹ si orin yi lo jẹri pe o kun fun ọgbọn ati oye eleyi to papọ mọ asa Ilorin gẹgẹ bi ilu ti Islamuu fidi mulẹ.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Bawo ni orin Dadakuada ṣe bẹrẹ?

Ọjọgbọn Abdulrasheed Na'Allah ninu apilẹkọ rẹ salaye pe orisun orin dadakuada wa lati ibi Egungun ilẹ Yoruba.

Ijala, ọfọ pipa ati orin eebu jẹ apẹrẹ orin taa le ri ninu dadakuada.

Àkọlé fídíò, OLota

Lode oni, ko fẹ ẹ si apẹrẹ orisun Egungunninu orin naa nitori bi awọn akọrin dadakuada ti se ti fi ọrọ ẹsin Islamuu se opo to mu orin wọn ro.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Kini yoo ṣẹlẹ lẹyin ifẹyinti Jaigbade Alao?

Bayi ti Jaigbade Alao wa pe ẹni ọgọfa ọdun o tọ ki a wo ipa to ko ninu orin ibilẹ yi ka si beere pe se awọn ti yoo sele de lẹrin rẹ ti wa bayi.

Ọpọ lo mọ orin dadakuada nipasẹ Jaigbade Alao.

Àkọlé fídíò, Alhaji Shanko

Ninu orin rẹ, o mu iyipada ba dadakuada pẹlu bo se n yi awọn orisi orin mii pẹlu rẹ.

Baa se n ri Fuji, Waka ati Juju ninu dadakuada bẹẹ naa lo yi orin ẹmi naa sinu rẹ to si jẹ ki awọn eeyan nifẹ si orin dadakuada.

Àkọlé fídíò, Recycle Tyres: Wo bí wọ́n ṣe fi àlòkù táyà ṣe bàtà, ẹní onírọ́bà, táìsì àtí ẹ̀ṣọ́ ilé míì

Se dadakuada ti wa de opin bayi ti Jaigbade fẹyinti nidi orin?

Idahun si ibeere yi jẹyọ lasiko to se afihan ọmọ rẹ Muhammad Jamiu fun Oba ilu Ilorin.

Arakunrin naa jẹwọ ara rẹ pẹlu orin nipa kiki Oba Ilorin to si fi han pe Jaigbade le ti fẹyinti nidi orin sugbọn awọn to n se'lede rẹ naa ko gbẹyin.