Tanzania bans babies from classrooms: Ìjọba Tanzania fòfin de gbígbé ọmọ wá sí kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́

Àsìá Orílẹ̀èdè Tanzania

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Tanzania kò ní sí ilé isẹ́ sí Jerusalem

Minisita eto ẹkọ lorilẹ-ede Tanzania, Adolf Mkenda, sọ pe bi ijọ̀ba ṣe faaye gba awọn akẹkọọbinrin lati tẹsiwaju pẹlu ẹkọ wọn lẹyin ti wọn ba bimọ, ko tumọ si pe wọn le gbe ọmọ wa si kilaasi.

Ọrọ to sọ yii jẹyọ lẹyin ti BBC ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ọdọmọbinrin kan to gbe ọmọ rẹ oṣu mẹrin wọ kilaasi ni ẹkun Mbeya.Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ọmọ lọ́wọ́

BBC yaworan Esnath Gideon, ẹni ọdun mọkandinlogun naa pẹlu ọmọ rẹ to gbe le ori itan nibi to joko si ni kilaasi.

O sọ fun BBC pe oun ko ni ẹni to le ba oun tọju ọmọ tuntun naa nile, lo mu ki oun gbe wa si kilaasi.

Ṣugbọn, Ọjọgbọn Mkenda sọ pe gbigbe ọmọ tuntun wa si kilaasi yoo ma a ṣe idiwọ fun awọn akẹkọọ yoku.

Ṣaaju asiko yii ni Tanzania, ijọba ma n le awọn akẹkọọbinrin to ba loyun kuro nile ẹkọ ni. Wọn kii si gba wọn laaye ki wọn o pada.

Oṣu Kejila, ọdun to kọja ni ijọba ṣe atunsẹ si ofin naa lẹyin ọdun mọkandinlogun.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Igbesẹ naa si ti mu ki ọpọlọpọ awọn akẹkọọbinrin to bimọ pada sile ẹkọ lati pari.

Lara ọna abayọ ti awọn onimọ fun ijọba fun iru awọn eeyan bi Arabinrin Gideon ni pe ko ṣe ibudo kan ti awọn akẹkọọ ti ko ba ri ẹni ti yoo ba wọn tọju ọmọ, le gbe ọmọ si fun amojuto.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ tẹlẹ?

Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ọmọ lọ́wọ́

Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan ní orílẹ̀ èdè Tanzania ti padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ lẹ́yìn tí ìjọba mú àyípadà bá òfin tó de àwọn obìnrin tó bá lóyún ní orílẹ̀ èdè náà.

Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ọmọ lọ́wọ́ lẹ́yìn tí ìjọba mú àyípadà bá òfin ilẹ̀ Tanzania.

Esnath Gideon

Esnath Gideon sọ fún ikọ̀ ìròyìn BBC pé òun kò ní ẹni tí òun yóò gbé ọmọ oṣù mẹ́rin òun fún ṣùgbọ́n inú òun dùn pé àwọn olùkọ́ gbà kí òun gbé ọmọ náà wọ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún náà ni ó ti kọ́kọ́ sọ ìrètí nù lórí píparí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbà tí ó lóyún ní ipele ẹ̀kọ́ kẹrin ṣùgbọ́n tó fi ìdùnú hàn pé òun le padà sẹnú ẹ̀kọ́ lẹ́yìn tí òun bí ọmọ náà tán.

Bawo ni Esnarth ṣe bẹrẹ irinajo rẹ?

Esnath Gideon ní iṣẹ́ agbẹjọ́rò ló wu òun láti ṣe tí òun yóò sì fojú sí ẹ̀kọ́ òun dáadáa.

"Ọmọ mi máa ń'ṣe ìdíwọ́ fún mi ní kílàsì ṣùgbọ́n mò ń fetí sílẹ̀".

Ní ọ̀dọ̀ ìyá àgbà tó ń ta samosa lọ́jà ní Esnath Gideon ń gbé tí inú rẹ̀ sì dùn pé ó padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀ nítorí ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún un nígbà tí ó lóyún.

Aare wo lo yi ofin naa pada?

Ààrẹ àná, John Magufuli ló fòfin dè é pé akẹ́kọ̀ọ́ tó bá lóyún àti àwọn tó bá ń tọ́mọ kò gbọdọ̀ lọ sílé ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n tí Ààrẹ Samia Suluhu ti mú àyípadà bá òfin náà.

Kò dín ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin olóyún 1,500 tí wọ́n lé kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ ẹkùn Mbeya.

Àmọ́ ní báyìí àwọn 240 ló ti padà sẹ́nu ẹ̀kọ́, tí wọ́n sì ti ṣètò láti kọ́ wọn ní àwọn ohun tí wọ́n pàdánù lásìkò náà láàárín ìgbà péréte.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere