Alleged ritual killing: Ọlọ́pàá nawọ́ gán tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú ilé

Oríṣun àwòrán, Other
Àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti nawọ́ gán tọkọtaya kan tó ń gbé ní ojúlé 72, MKO Abiola way, Leme ní ìlú Abeokuta fún ẹ̀sùn pé wọ́n ní ẹ̀yà ara ènìyàn nílé.
Àwọn tọkọtaya náà ni Kehinde Oladimeji ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì àti ìyàwó rẹ̀, Adejumoke Raji, ẹni ọdún márùndínlógójì.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi ní inú ike ńlá kan nínú yàrá àwọn tọkọtaya náà ní àwọn ti bá àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ara ènìyàn.
- Mubarak, tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè Ibadan lọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ikú rẹ̀ - àwọn ọ̀rẹ́ kọrin arò lẹ́yìn rẹ̀
- Ẹ dẹ́kun bíba ìjọba lórúkọ jẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo
- Ipò Ààrẹ gbọdọ̀ padà sí ẹkùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún 2023 - Afenifere
- "Ìná tó ń ṣe àkóso ojú pópó ló dá ọkọ̀ agbówórìn dúró, tí adigunjalè fi kọ lù ú"
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Ìyá Sunday Igboho wà lórí àìsàn torí kò rí ọmọ rẹ̀ - Agbekoya
- Davido, bá mi kọ ẹsẹ orin kan nínú àwo orin mi, jẹ́ ká da ayé láàmú - Portable Zazzu
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
Oyeyemi ní àwọn tọkọtaya náà ní oníṣègùn làwọn àti pé àwọn ara náà tó jẹ́ ọwọ́, ọmú àti àwọn mìíràn ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Micheal, tó ń gbé ní Adatan gbe sí àwọn lọ́dọ̀.
Ó ṣàlàyé pé gbogbo ìgbìyànjú láti nawọ́ gán Micheal náà ló já sí pàbó bí àwọn afurasí náà kò ṣe mọ ilé rẹ̀ mọ̀.
Báwo ni wọ́n ṣe nawọ́ gán wọn?
Oyeyemi ṣàlàyé pé Baálẹ̀ Leme, olóyè Moshood Ogunwolu ló mú ẹjọ́ lọ sí àgọ ọlọ́pàá Kemta pé ọkùnrin kan, Pásítọ̀ Adisa Olanrewaju, tó jẹ́ alábàgbé àwọn afurasí náà, wá fi ẹjọ́ sun òun pé àwọn ń gbọ́ òórùn tí kò dára láti yàrá àwọn afurasí ọ̀hún.
Èyí ló mú kí DPO àgọ́ ọlọ́pàá Kemta ní kí àwọn ọlọ́pàá lọ ṣe àyẹ̀wò yàrá àwọn afurasí yìí níbi tí wọ́n ti bá àwọn ẹ̀ya ara náà nínú ike kan.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Lanre Bankole ti wá pè fún títarí ẹjọ́ náà sí ẹ̀ka tó wà fún ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ náà (CIID) fún ìwádìí ìjínlẹ̀.
Kọmíṣọ́nà náà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò fojú winá òfin.
Ẹ ó rántí pé ní bíi ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ni wọ́n bá òkú ènìyàn kan tí ẹ̀yà ara kò pé ní agbègbè Leme.
Oyeyemi ní ìwádìí kò ì tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ara òkú náà ni wọ́n yọ èyí tí wọ́n bá nínú yàrá àwọn afurasí yìí.












