2023 elections: Afenifere ní ipò Ààrẹ gbọdọ̀ padà sí ẹkùn gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́dún tó ń bọ̀

Ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá ti lùlù àtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ àwọn gómìnà gúúsù ilẹ̀ gúúsù Nàìjíríà (SGF) lórí pé ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejì ni Gómìnà Rotimi Akeredolu ti ìpínlẹ̀ Ondo tó jẹ́ alága SGF sọ fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìṣípò agbára ìyẹn "Power Shift Movement" pé ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023 nígbà tí wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí i ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní Akure.
Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ Afenifere, Jare Ajayi ní ẹgbẹ́ náà ti kọ orin àtìlẹyìn kín ọ̀rọ̀ tí Akeredolu sọ yìí èyí tí àwọn ẹgbẹ́ ilẹ̀ Árèwá méjì ìyẹn Arewa Consultative Forum (ACF) àti Coalition of Northern Groups (CNG) ti ń takò.
- Mubarak, tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè Ibadan lọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ikú rẹ̀ - àwọn ọ̀rẹ́ kọrin arò lẹ́yìn rẹ̀
- Ẹ dẹ́kun bíba ìjọba lórúkọ jẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo
- "Ìná tó ń ṣe àkóso ojú pópó ló dá ọkọ̀ agbówórìn dúró, tí adigunjalè fi kọ lù ú"
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Ìyá Sunday Igboho wà lórí àìsàn torí kò rí ọmọ rẹ̀ - Agbekoya
- Davido, bá mi kọ ẹsẹ orin kan nínú àwo orin mi, jẹ́ ká da ayé láàmú - Portable Zazzu
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
Afenifere ní ipò Gómìnà Akeredolu wà ní ìbámu pẹ̀lú ìrètí àti ìfẹ́ àwọn ènìyàn ẹkùn ìwọ̀ oòrùn, ìlà oòrùn, àti ààrin gbùngùn gúúsù Nàìjíríà tí wọ́n parapọ̀ dá ẹgbẹ́ "South and Middle Belt Leadership Forum" kalẹ̀.
Ajayi ní gbogbo àwọn aṣojú wọn wọ̀nyìí ló péjú síbi ìpàdé tí wọ́n ṣe pẹ̀lú gómìnà Akeredolu.
Ó ní gbogbo àwọn ni àwọn jọ ni Nàìjíríà, ẹ̀yà kan kò sì gbọdọ̀ máa jẹ gàba lé àwọn yòókù.
Ó fi kun pé ẹkùn Arewa ti lo ọdún mẹ́jọ tí Ààrẹ Muhammadu Buhari bá ti parí sáà rẹ̀ lórí àléfà, ó sì di dandan kí ipò náà padà sí ẹkùn gúúsù Nàìjíríà.
Bákan náà ló rọ ACF àti CNG láti bá àwọn ènìyàn wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n máa ṣọ́ ìwà àti ọ̀rọ̀ wọn èyí tó le da omi àláfìà rú.
Kíló ṣẹlẹ̀ gan an?
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹjọ, oṣù kejì ni Gómìnà Rotimi Akeredolu ní ipò Ààrẹ gbọdọ̀ wá láti ẹkùn Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí lọ́dún 2023 à ti pé ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá mú olùdíje wá láti ẹkùn árèwá yóò fìdí rẹmi.
Gómìnà Akeredolu, nígbà tó gbàlejò ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìṣípò agbára ìyẹn "Power Shift Movement" èyí tí alága wọn Dókítà Pogu Bitrus kó sòdí, sọ pé àwọn gómìnà gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà nínú àwọn ìpàdé àwọn ti fẹnukò pé ipò Ààrẹ gbọ́dọ̀ wá láti ẹkùn àwọn lọ́dún 2023.
Báwo ni Arewa ṣe gba ọ̀rọ̀ yìí?
ẹ̀wẹ̀, lọ́jọ́ rú ni àwọn agbẹnusọ ACF, Emmanuel Yewa àti CNG, Abdul-Azeez Suleiman nínú àtẹ̀jáde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ju òkò ọ̀rọ̀ lu gómìnà Akeredolu pé kò fẹ́ràn àwọn ènìyàn ẹkùn árèwá.
Yawe àti Suleiman ní ọ̀rọ̀ Akeredolu sọ yìí dàbí èyí tó fi ń dúnkokò mọ́ ẹkùn arewa ni












