2023 Presidential Election: Wo Ìyá ẹni ọdún 102 tó fẹ́ díje du ipò Ààrẹ Naijiria lọ́dún tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, @Africa_Archives
Iya ẹni ọdun mejilelọgọrun kan ti kede erongba rẹ lati dije du ipo Aarẹ Naijiria ninu eto idibo gbogbogo ti yoo waye lọdun 2023.
Iya agba naa, Nonye Josephine Ezeanyaeche sọ pe oun ni erongba rere fun Naijiria ti awọn araalu ba le dibo yan oun.
Ezeanyaeche, ti ọpọ ti apẹle rẹ n jẹ "Mama Africa' tabi 'living legend' jẹ ọmọ bibi ilu Aguata, ni ipinlẹ Anambra.
- Ààrẹ Mozambique tẹ́lẹ̀ rí jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan ọmọ rẹ̀
- Ẹnikẹ́ni tó bá tún fi ìyà jẹ òṣìṣẹ́ LASTMA l'Eko yóò fojú winá òfin- Ọ̀gá LASTMA
- Yàtọ̀ sí Bimbo Success àti Kemi Korede, wo àwọn míì tí wọ́n ń pariwo Funke Akindele kiri
- Àwọn òṣìṣẹ́ wa kò lọ́wọ́ nínú gbígbé egbògi olóró - NDLEA
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi buwọ́lu ₦30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ
- Ǹjẹ́ ó mọ̀ nípa Álífábẹ́ẹ̀tì Oduduwa àti bí o ṣe lè lòó fi gbé èdè Yorùbá ga?
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjà ti bẹ́ sílẹ̀ láàrín Pasuma àti 'Manager' rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ owó?
Oun naa si ni oludasilẹ ẹgbẹ 'Voice for Senior Citizens of Nigeria' eyii to jẹ ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ awọn arugbo ni Naijiria.
Nigba to n sọrọ lorukọ iya agba aa, aarẹ ẹgbẹ ọhun, Caro Nwosu ni "Ti awọn ọmọ Naijiria ba kọ lati kopa ninu eto oṣelu, mama ti sọ pe oun ti sẹtan lati dije du ipo."
"O ti ni alakalẹ awọn eto to fẹ fi tukọ Naijiria, o si ni ero rere fun Naijiria, iyẹn ti awọn eeyan gidi ba kọ lati wa dije."
Iroyin ni iya naa ti gba oniruru ami ẹyẹ fun akitiyan rẹ si ẹtọ ọmọniyan ati atunṣẹ orilẹ-ede.
Lara awọn ami ẹye to ti gba ni ami ẹye alaafia ilẹ Afrika, iyẹn African Peace Award, ti ọdun 2021.
Ni bayii, iya agba naa ti darapọ mọ awọn eeyan ti wọn ti fi erongba wọn lede lati tukọ Naijiria lọdun to n bọ.
Ki ni awọn eeyan n sọ nipa erongba iya yii?
Awọn ọmọ Naijiria kan ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lẹyin ti mama agba naa kede erongba rẹ tan.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ti irufẹ eeyan bii Muhammadu Buhari ati Bola Tinubu ba le tukọ Naijiria, mama naa ni ẹtọ sii, lawọn mii n sọ pe eremọde lasan ni iya agba naa n ṣe.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bẹẹ lawọn mii n sọ pe mama ọhun yoo ṣiṣẹ ju Aarẹ to wa lori bayii oye lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ẹwẹ, ọpọ awọn mii ni ki mama "lọ sẹmpẹ" nitori awọn ko fẹ arugbo ni ipo oṣelu mọ.
- Wo ohun tí ìjọba ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ kílààsì SS 2 tó gbá Olùkọ́ létí ní Ibadan
- Amotekun Ondo gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ àjàgbé tó ń kó àwọn ọ̀dọ́ 63 láti Gombe lọ sí Eko
- Òní ní Oloye Christopher Adebayo Alao Akala yóò wọ káà ilẹ̀ lọ ní Ogbomoṣo
- Ìwádìí tó kúná ni a fẹ́ láti mọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ olóògùn owó ní Oja Odan- Oba Oladiipo Oyebamiji
- EFCC gbẹ́sẹ̀lé dúkìá ọ̀gá olọgun tí iye rẹ̀ tó ₦10.9b
- Wọ́n ti fi orúkọ Sadio MAne sọ pápá ìṣeré kan ní Senegal
















