Oduduwa alphabets: Ǹjẹ́ ó mọ̀ nípa Álífábẹ́ẹ̀tì Oduduwa àti bí o ṣe lè lòó fi gbé èdè Yorùbá ga?

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa ni Ile Ife
Àkọlé àwòrán, Oba Dr Olusino Adekoya ati Oba Oyeniran Ishola Ojudu 2 Onisabe Benin Republic

Njẹ o mọ pe alifabẹẹti Oduduwa wa yatọ si alifabẹẹti ede Yoruba ati Oyinbo?

Ọpọ ọmọ Yoruba ni ko mọ pe alifabẹẹti tiwa n tiwa ti wa tipẹ lati aye Odududuwa to jẹ baba gbogbo ẹya Yoruba.

Koda o ni ilana iwe kikọ to jẹ ti Yoruba gan an tawọn Yoruba ti n lo ṣaaju alifabẹẹti tawọn Oyinbo gbe wa ninu ede Yoruba ati ede Gẹẹsi.

Ile ẹkọ kan to n ṣe agbatẹru kikọ Alfabẹẹti Oduduwa, Oduduwa Alphabetic Academy School wa ni Ajase ni orilẹ-ede Benin Republic nibi ti wọn ti tan mọ iran Yoruba.

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa ni Ile Ife
Àkọlé àwòrán, Mr Yankoty Charlemont tó jẹ́ Mayor lati Portnovo ni Republic of Benin

Ni bayii, ile ẹkọ naa n ṣe ayẹyẹ ikẹkọọ gboye alakọkọ iru rẹ ni fasiti OAU ni ILe Ife lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2022

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa
Àkọlé àwòrán, Oba Olawuni Bamijogun Badru Alao tó jẹ Akire Ile Ife to ṣoju fun Ooni Adeyeye Ogunwusi nibi eto naa

Bakan naa ni wọn tun ṣe ajọdun ọdun mẹfa ti wọn da ile ẹkọ ọhun silẹ

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa
Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa ni Ile Ife
Àkọlé àwòrán, Awọn Ori Ade lati orileede Republ;ic Of Benin

Wọnyii diẹ lara awọn fọto lat ibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade ni ile ẹkọ naa.

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa

Oloye Popo Toluwalase ni o ṣe agbateru ile eko naa ti ọpọ ọmọ Yoruba atata ti kẹkọọ gboye bayii.

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa
Àkọlé àwòrán, Oloye Popo Toluwase to jẹ agbatẹru ile ẹkọ ti wọn ti n kọni nipa alifabẹẹti Oduduwa ni orile-ede Benin Republic

Ilé ẹ̀kọ́ Oduduwa Alphabetic Academy ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Benin Republic lati tubọ gbe ogo aṣa ati igbagbọ Yoruba ga kaakiri agbaye.

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa
Àkọlé àwòrán, Die lara awọn akẹkọọgboye jade ti wọn n fi ede ati aṣa Yoruba da bira ni orilẹ ede Benin Republic

Okan lara awọn to tun sọrọ itẹsiwaju nibi eto naa ni komiṣọnna aṣa ati irinajo afẹ fun ipinlẹ Osun, Ogbeni Obawale Adebisi.

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa ni Ile Ife
Àkọlé àwòrán, Komiṣonna Obawale Adebisi to jẹ Komiṣọnna Aṣa ati Irinajo afẹ ni ipinlẹ Osun lasiko to n sọrọ nipa pataki ede Yoruba

Komiṣọnna naa to ṣoju gomina Gboyega Oyetola nibẹ sọrọ nipa pataki kikọ awọn ọdọ asiko yii nipa ede Yoruba sii ki iwa ọmọluwabi le pada si awujọ wa.

Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa ni Ile Ife
Àkọlé àwòrán, Lara awọn ori ade lati Benin Republic nibẹ
Ayẹyẹ ikẹkọọ jade ile ẹkọ alifabẹẹti Oduduwa ni Ile Ife
Àkọlé àwòrán, Awọn Ori ade miran nibi eto ọhun ni ile Ife