NNPC fuel scarcity: Kìí ṣe pé a mọ̀ọ́mọ̀ kó epo tí kò dáa wọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si ọrọ epo bẹntiro ni naijiria, NNPC ti sọ pe kii ṣe pe awọn mọọmọ ko epo bẹntiro ti ko dara wọ Naijiria.
NNPC ni ọna kan ṣoṣo ti awọn le fi mọ pe epo naa ni eroja "mathanol" to ba epo naa jẹ ni ki awọn ṣayẹwo rẹ ki wọn to ko wọ Naijiria, amọ igbesẹ naa kii ṣe dandan.
Adari ajọ naa, Male Kyari lo fi ọrọ naa lede niwaju igbimọ to n ṣewadii ọwọngogo epo to wa lode, eyii ti ile igbimọ aṣoju-ṣofin gbe kalẹ.
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Ìwádìí tó kúná ni a fẹ́ láti mọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ olóògùn owó ní Oja Odan- Oba Oladiipo Oyebamiji
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Algeria yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní san N41,000 fáwọn ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe lóṣù tó ń bọ̀
- Amotekun Ondo gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ àjàgbé tó ń kó àwọn ọ̀dọ́ 63 láti Gombe lọ sí Eko
O ni "Ko ṣeeṣe ki a mọọmọ ko epo ti yoo pa awọn araalu lara wọ Naijiria."
"Bẹẹni ko si bi a ṣe le mọ pe epo naa ni methanola ninu ayafi ti awọn ti alagbata ba sọ fun wa, amọ ko pan dandan labẹ ofin ki wọn ṣe beẹ."
Kyari ni NNPC ko mọ pe methanol wa ninu epo ti wọn ko wọle, awọn si ti gbe igbesẹ lati ṣe atunṣẹ lori iṣẹlẹ naa.
O ni kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn yoo ko epo wọle lati ibudo ti epo ọhun gba wọ Naijiria, ibudo naa si jẹ ọkan gboogi ti awọn orilẹ-ede nilẹ Afrika ti maa n ra epo ti wọn.
Lẹyin naa lo ni ki awọn ọmọ Naijiria ma ba ọkan jẹ nitori lita epo to le ni biliọnu meji ni awọn yoo ko wọ Naijiria titi ipari oṣu Keji ti a wa yii.
Ati pe awọn ti dari gbogbo ile epo NNPC ni Naijiria lati maa ta epo fun wakati mẹrinlelogun lọna ati maye dẹrun fun araalu.
Awọ iṣoro marun un ti awọn ọmọ Naijiria n koju nitori ọwọngogo epo to wa lode
1. Sunkẹrẹ fakẹrẹ loju popo
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n farada sunkẹrẹ-fakẹrẹ loju popo bayii nitori ọwọngogo epo to wa lode.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ilu ti sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa ti milẹ julẹ ni ilu Eko, Abuja, Ibadan, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Eyii ko ṣẹyin bi ọpọ ero ṣe n to lọwọwọ lati ra epo, eyii to n di oju popo fun awọn ẹlomiran.
2. Owo ọkọ gbowolori
Gbogbo igba ti epo ba ti wọn ti ni owo ọkọ yoo le si, eyii to maa n fa inira fun awọn araalu.
Yatọ si owo ọkọ to lọ soke, owo awọn nnkan miran bii ounjẹ naa tun ti gbowolori, eyii ko si ṣẹyin owo ọkọ to le si.
- Ẹgbẹ́ Olùkọ́ Fásitì ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì olóṣù kan lónìí
- Oríṣìíríṣìí aṣọ aláràǹbarà láwọn òṣèré tíátà fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́
- Àgbáríjọpọ̀ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani
- A ṣì lè yanjú ọ̀rọ̀ Ukraine ní ìtùbí-ìnùbí - Russia
- Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ọmọ ọdún kan àti oṣù méje pa ní ìpínlẹ̀ Delta, O bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá
- Tí o bá ń pẹ́ jẹun alẹ́, o lè ní àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti asétọ̀
3. Iye akoko ti awọn eeyan n lo nile epo
Lọpọ igba, awọn mii maa n wa nile epo bẹntiro lati aarọ titi di aṣalẹ, koda awọn mii a maa sun ile epo mọju lọna ati tete ri epo ra laarọ ọjọ keji.
Eyii ko ṣẹyin bi ero ṣe maa n pọ lapọju lawọn ile epo naa.
4. Iye owo gan ti wọn n ta epo
Gbogbo igba ti epo ba ti wọn ni awọn ile epo maa n gbe owo le lori.
Lara awọn eeyan to ṣabẹwo sile epo kaakiri Naijira jabọ fun BBC pe oniruru iye lawọn ile epo n ta jara lita lagbegbe awọn.
Fun apẹrẹ, Sulaiman Abdulkarrem Mashegu to wa ni Kuje, niluu Abuja sọ pe N650 ni wọn n ta jara epo ladugbo oun.
Nigba ti Fodio Muawiyyah Bodinga to n gbe ni Sokoto sọ pe owo epo naa wa laarin N300 si N400 ladugbo oun.
5. Oniruru ede aiyede ati ija nile epo
Eyii ni ohun to buruju nipa ọwọngogo epo ni Naijiria.
Lọpọ igba ti epo ba wọn ni ija maa n bẹ silẹ lawọn ile nitori awọn ti wọn ba fẹ tete ra epo tiwọn tabi awọn ti wọn ko fẹ to sori ila.
Idi ree ti ọpọ kii ṣe fẹran lati maa ra epo titi di akoko ti epo naa ba ti wa nilẹ lọpọ yanturu.





















