Oyo suspends student: Wo ohun tí ìjọba ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ kílààsì SS 2 tó gbá Olùkọ́ létí ní Ibadan

Oríṣun àwòrán, @Seyi Makinde
Akẹkọọ oni ipele karun un ilé ẹ̀kọ́ girama ni ipinlẹ Oyo lo ṣe bẹbẹ ninu kilaasi ti awọn akẹgbẹ rẹ si ṣe ha!
Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti ní kí akẹ́kọ̀ọ́ girama onípele kejì (SS 2), Roqeeb Ojo, tí ilé ẹ̀kọ́ Anglican commercial Secondary School, Orita-Mefa, Ibadan, lọ rọ́kún nílé fún oṣù kan fẹ́sùn wí pé ó gbá Àgùnbánirọ̀ kan tó jẹ́ olúkọ̀ rẹ̀ létí.
Kọmíṣọ́nnà fún ètò Ẹ̀kọ́, Sáyẹ́ǹsì àti Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìpínlẹ̀ Oyo, Rahman Abdu-Raheem ló léde ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
- Yàtọ̀ sí Bimbo Success àti Kemi Korede, wo àwọn míì tí wọ́n ń pariwo Funke Akindele kiri
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjà ti bẹ́ sílẹ̀ láàrín Pasuma àti 'Manager' rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ owó?
- Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé o fí agídí bá ọmọdé lòpọ̀
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi buwọ́lu ₦30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ
- Amotekun Ondo gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ àjàgbé tó ń kó àwọn ọ̀dọ́ 63 láti Gombe lọ sí Eko
- Ẹ̀yin ará ìlú ẹ má bìnú, kìí ṣe pé a mọ̀ọ́mọ̀ kó epo tí kò dáa wọ Naijiria
Kini Komiṣọnna sọ fun Obi akẹkọọ naa?
Abdu-Raheem nígbà tó ń fi lẹ́tà ìdádúró náà lé àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún lọ́wọ́ ní ó jẹ́ ohun tó burú jáì tó sì bu omi tútù sọ́kàn ẹni wí pé akẹ́kọ̀ọ́ le gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti gbá olùkọ́ létí.
Ó ní lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ bá padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ lẹ́yìn ìdádúró oṣù kan tí wọ́n fún un, ó gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ olùkọ́ náà à ti pé yóò tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pé òun kò ní dá aṣọ irú rẹ̀ ṣorò mọ́ láéláé.
Kini Kọmiṣonna naa sọ fun akẹkọọ naa?
Bákan náà ló rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ aṣojú rere fún àwọn òbí wọn, ilé ẹ̀kọ́ wọn àti ìpínlẹ̀ Oyo lápapọ̀ nípa híhu ìwà ọmọlúàbí ní gbogbo ibikíbi tí wọ́n bá ti bá ara wọn àti pé ìjọba kò ní fàyè gbá ìwà kòtọ́.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣèkìlọ̀ pé ẹni tí irúfẹ́ ìwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí òmíràn bá tún ṣí mọ́ lórí, àwọn yóò le kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ pátápátá ni.
Abdu-Raheem tún pàrọwà sáwọn olùkọ́ láti ní ìfarajìn sí iṣẹ́ wọn.
















