Osun PDP Crisis: Kí ló fa làásìgbò níbí ìpàdé PDP tó mu kí ọmọ ẹgbẹ́ kan náà doju ìja kọ ara wọn?

Mọto ti wọn da ina sun

Oríṣun àwòrán, Official Osun PDP Group page

Kangun kangun kangun, o ti kangun sibi kan bayii lori aawọ to n da omi alaafia ẹgbẹ oselu PDP ru nipinlẹ Osun.

Koda aawọ naa ti da yanpọnyanrin silẹ, to si mu ẹmi eeyan meji lọ nigba ti ọpọ eeyan miran fara pa.

Se ni rogbodiyan nla gbode lasiko ipade apapọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa to waye nijọba ibilẹ kọọkan.

Ipade naa ni wọn se lati yan awọn ọmọ ẹgbẹ ti yoo jẹ asoju nibi ipade ibo abẹnu fun yiyan oludije fun ipo gomina ti yoo gbe asia ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ naa.

Ọjọ Aje, ọjọ Keje osu Kẹta to n bọ si ni ibo abẹnu lati yan oludije gomina naa yoo waye.

Àkọlé fídíò, Aje Games: Eré ayò ọrọ̀ ajé ló ń wá ọ̀nà àbáyọ sáwọn ìṣòro tó ń bá Yorùbá fínra

Ki lo fa wahala to suyọ nibi ipade PDP Osun:

Nibi ipade awọn ọmọ ẹgbẹ to waye yika gbogbo ijọba ibilẹ to n bẹ nipinlẹ Osun ni, se ni wahala su yọ lawọn ijọba ibilẹ bii marun.

Asiko rogbodiyan naa si ni ẹmi eeyan meji bọ, ti ọpọlọpọ miran si fi ara pa.

Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ oselu PDP ti pin si igun meji nipinlẹ Osun, ti igun mejeeji si n koju ara wọn lati fa oludije kalẹ fun ipo gomina lati soju ẹgbẹ oselu naa.

Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ti fidi isẹlẹ naa mulẹ fawọn akọroyin nilu Osogbo.

Eeyan to ku ninu laasigbo naa

Oríṣun àwòrán, Official Osun PDP Group page

Ọlọpaa kede orukọ eeyan meji to ku nibi ipade PDP Osun:

Opalola ni ọkunrin kan to n jẹ Toheeb Mutallib lati wọọdu kẹrinla to wa ni adugbo Oke-Oba-Agberire nijọba ibilẹ Iwo, jade laye.

Bakan naa lo ni Aremu Olamide naa ku nilu Ipetumdu to ba nijọba ibilẹ Ariwa Ife.

Yatọ si eyi, o tun fidi rẹ mulẹ pe ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP lo fi ara gbgbẹ lorisirisi nigba ti awọn janduku oloselu gbidanwo lati da ipade naa ru.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Awọn agbegbe ti wahala ti bẹ ilẹ ree:

Awọn ijọba ibilẹ ti idarudapọ naa ti waye ni Ede, Osogbo, odo-Otin, Olorunda, Iwo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Se ni wọn tun jo awọn dukia kan nina, to fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ kan nilu Ipetumodu.

Ẹgbẹ oselu PDP se ipade apapọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ni ijọba ibilẹ kọọkan to wa nipinlẹ naa ni ọjọru.

Nibi ipade apapọ naa ni wọn yoo ti yan apapọ awọn asoju mẹta lati wọọdu ojilelọọdunrun o din mẹjọ to wa nipinlẹ naa.

Awọn asoju naa si ni yoo lọ soju ijọba ibilẹ koowa wọn nibi idibo abẹnu ẹgbẹ oselu naa ti yoo waye ni ọjọ Keje osu kẹta.

Nibi idibo abẹnu ọhun si ni wọn yoo ti dibo yan oludije gomina ti yoo gbe asia ẹgbẹ PDP nibi ibo gomina ipinlẹ naa ti yoo waye lọdun yii.