Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Bo se wu Oluwa, lo n se ọla, oun si ni alamọ to mọ awa ẹda, ohun to ba si wu, lo le fi wa mọ.

Ni ọpọ igba ni ọkan awa ẹda maa n poruru lori idi ti Eledua fi se awọn nkankan amọ ti a ko ni idahun si nitori Ọba aseyiowu ni Oluwa.

Bi Ọlọrun si se da awọn abarapa, lo da awọn akanda ẹda, ti ẹya ara wọn ko pe, amọ gbogbo ẹda isẹ ọwọ rẹ lo n tọju wọn, to si n pese jijẹ-mimu fun.

Obinrin kan ree, Bukola Odufuwa, ti ko le naro soke, ti ẹyin rẹ si tẹ, koda, ẹsẹ rẹ gan lọ.

Ibeere ti yoo si kọkọ gba ọkan ẹni to ba se alabapade obinrin naa ni pe ki lo de, to fi ri bẹẹ?

Wọn yoo si maa beere lọkan ara wọn pe se isẹ ọwọ Ọlọrun ni abi afọwọfa abi ijamba lo sọ da bẹẹ?

Ki lo fa ailera ba Odufuwa?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to mu ko di alailera, arabinrin Odufuwa, tii se ọmọbibi Ijebu ni kekere ni isẹlẹ naa ti sẹlẹ si oun.

O ni afẹfẹ kan lo sadede fẹ lu oun nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun meji, lati igba naa wa si ni ẹyin oun ti tẹ, ti ẹsẹ oun si lọ.

O fikun pe oun ti n lọ sile ẹkọ nigba naa, ti oun si le rin daadaaa amọ isẹlẹ afẹfẹ to fẹ yii, lo pa kadara oun da.

Ọkọ mi sa lọ lẹyin ọmọ meji tori awọn obi rẹ ni ko ma fẹ mi:

Nigba to n salaye irinajo rẹ ati bo se di iya ọlọmọ meji, Odufuwa ni oun kuku ni ọkọ ri.

O sọ pe oun se alabapade ọkunrin kan, ẹni to fun oun loyun, ko to mu oun lọhan awọn obi rẹ.

Amọ ni kete ti awọn obi ọkunrin naa foju kan oun, ni wn yari pe ko le fẹ oun nitori pe oun jẹ akanda ẹda.

O ni oun bimọ meji amọ ọkọ oun naa ti sa lọ lai boju wẹyin.

Emi kii tọrọ agbe jẹun nitori pe mo nisẹ lọwọ:

Amọ bi Odufuwa se jẹ akanda ẹda to yii, o yari pe oun kii tọrọ agbe jẹun nitori oun ni awọn isẹ ti oun n se.

“Yatọ si pe mo n se ounjẹ ta fun awọn ọmọ ile ẹkọ, mo le gba ilẹ, pọn omi, tọju ọmọ, ti mo si tun le fọ asọ.

Ailera yii ko sọ mi di ọlẹ, mo n gbiyanju agbara mi bi o tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan maa n tiraka lati fun mi ni owo.

Amọ mo maa n sọ fun wọn pe n ko tọrọ agbe, ti wọn yoo si ni awọn mọọmọ saanu mi ni, maa sẹsẹ wa gba owo naa.”

Bi ironu ba wa, maa kọrin si Ọlọrun, ti ironu naa yoo si fo lọ:

Nigba to n sọrọ pe lootọ ni ipo ti oun wa maa n ko irẹwẹsi ba ọkan oun amọ Odufuwa ni oun kii gba ironu laaye lọ titi.

O ni se ni oun maa n kọrin iyin si Ọlọrun ti ironu ba wa, ti oun yoo si tete gbe ironu kuro ni ọkan.

O ni ko si ibi ti oun ko le lọ pẹlu bi oun se ri yii, ti oun si n ta ọja pẹlu.