Omoyele Sowore dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tó fara gba ọta gáàsì tajútajú níbi ìwọ́de kan nílùú Abuja

Oríṣun àwòrán, @GuardianNigeria
Ajafẹtọ ati oludije sipo Aarẹ Naijiria lọdun 2019, Omoyele Sowore ti ṣeṣe lẹyin to fara gba ọta gaasi tajutaju lasiko iwọde kan niluu Abuja.
Ṣaaju ni Sowore ati awọn oluwọde kan ti kọkọ korajọ siwaju Unity Fountain laarọ ọjọ Aje lati ṣe ifẹhonuhan lori eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro kọ lati jẹ ki Sowore ati awọn oluwọde akẹgbẹ rẹ wọle si gbọgan ọhun, ṣugbọn wọ yin gaasi tajutaju lati tu wọn ka.
- Ọkọ àti ìyàwó ri ọmọ ọdún kan àbọ mọlẹ láàyè lọgànjọ oru, àṣírí tú!
- Ọjọ́ kínní oṣù kẹfà ni Amotekun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni máa gbógun tàwọn ọ̀daràn àti ajínigbé nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ìdí tí ECOWAS fi dá Mali dúró, tó tún fún àwọn ológun ní gbèdéke láti gbé ìjọba sílẹ̀
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti kéde pé IPOB àti ESN ló pa Gulak tó kú lánàá
- Wo àsìkò tí ìdíje "BBNaija lockdown reunion" yóò bẹ̀rẹ̀
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun awọn akọroyin pe asiko ti ọkan lara awọn ọlọpaa naa yin gaasi ọhun ni ọta rẹ ba Sowore, to si ṣubu lẹsẹ kan naa.
Lẹyin naa ni wọn gbe ajijagbara naa digbadigba lọ sile iwosan fun itọju to peye.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ninu kan fidio to fi lede loju opo Twitter ati Facebook rẹ, Sowore ṣafihan oju egbo ti ọta naa ti ba a lẹṣẹ, to si n sọ fun awọn alatilẹyin rẹ pe ki wọn má da iwọde ọhun duro.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n sọ erongba wọn lede lori iṣẹlẹ naa lori ayelujara.
Lẹyin iṣẹlẹ ọhun ni minisita abẹle fun ọrọ Niger Delta, Festus Keyamo sọ loju opo Twitter rẹ pe ẹnikẹni to ba gba ọna miran lati paarọ ijọba to wa lori oye yatọ si eto idibi ti ṣẹ si ofin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Keyamo fi kun pe ẹṣẹ iditẹgbajọba ni ki eeyan gba ọna miran ti kii ṣe nipasẹ eto idibo lati da oju ijọba bolẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ree ti Sowore yoo gbiyanju lati gbena woju ẹkun ijọba Naijiria.
- Àwọn jàndùkú agbébọn yìnbọn pa ọkùnrin oníṣòwò kan nílùú Ibadan
- Ọwọ́ EFCC tẹ ọmọ Yahoo tó fẹ́ ra ọkọ̀ SUV tí iye rẹ̀ tó 44 mílíọ́nù pẹ̀lú Bitcoin
- Nǹkan bíi ọmọ ilé kéú 150 ni àwọn agbébọn jí gbé lọ ní Niger
- Ẹ̀mí àìrí lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde ni ilé ẹ̀kọ́ St Claire's ní Offa
- Ọjà olówó iyebíye jóná nínú ọjà Ladipo nílùú Eko














