Ghana couple buries son alive: Ọkọ àti ìyàwó ri ọmọ ọdún kan àbọ mọlẹ láàyè

Ọwọ ọlọpaa tẹ Paul Adobaw

Oríṣun àwòrán, Kofi Adjei

Ọwọ Ọlọpaa ti tẹ arakunrin kan ati iyawo rẹ ti wọn mu ni afurasi pe wọn sin ọmọ wọn ọmọ ọdun kan ataabọ laaye ni agbegbe Central Region ni Ghana.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ọkọ atiyawo pawọpọ pẹlu oniṣegun ibilẹ kan loru ọganjọ lati sin ọmọ naa.

Abubakar Mohammed to ni iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ latinu yara tirẹ sọ pe oun ri awọn mẹtẹẹta nita ti wọn n huwa lodi lodi.

"Bi mo ṣe wa ninu yara, mo ri i pe ọmọ kan wa lejika ọkan lara wọn ... Igba to ya ni mo ri i pe o dabii wipe wọn ti gbe ọmọ naa sin. O sọ eyi fun awọn oniroyin.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

"Torinaa, mo lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti to si jẹ pe lẹyin ti awọn ọlọpaa gbẹ ilẹ naa, a ri i pe lootọ lootọ ni wọn gbe ọmọ naa gbin sinu ilẹ". Ọgbẹni Abubakar fi kun un.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Central Region, DSP Irene Oppong ṣipaya rẹ pe "Abubakari fi ọrọ naa to awọn leti ni nkan bii ago mẹta oru.

Lẹsẹkẹsẹ ni ọlọpaa Ghana bọ sigboro ti wọn bẹrẹ si ni wa babalawo naa to ti fẹsẹ fẹẹ.

"A ri Paul Adobaw ti wọn mọ si Kojo Okor to jẹ onile rẹ ati obinrin meji ṣugbọn o dabii pe wọn ti pa ọmọ naa lara".

Ọlọpaa mu Paul Adobaw wọn si gbe e lọ si ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti wọn si ni ki afurasi naa hu ilẹ ti wọn ti da iyẹpẹ bo nibi ti wọn ti ri ọmọ naa to ti ku, Yaw Adobaw.

Wọn gbe oku ọmọ, lẹyin ti wọn si ṣe ayẹwo kikun, wọn ri i pe ẹjẹ n yọ ni imu ati ẹnu rẹ ki wọn to gbe e lọ si mọṣuari.

Ọwọ ọlọpaa tẹ Paul Adobaw

Oríṣun àwòrán, Kofi Adjei

Afurasi ọhun, Paul ti wa ni atimọle ọlọpaa to si n ran wọn lọwọ ninu iwadii ti wọn n ṣe. Ọlọpaa ṣi n wa babalawo to ti na papa bora.

Ileeṣẹ iroyin BBC ko iroyin jọ pe awọn oloye ati agbaagba adugbo naa n ṣe etutu lọwọ lọwọ lati ṣe iwẹnumọ ilẹ tori pe wọn ri ọmọ naa mọlẹ laaye.

Ko tii si aridaju idi kan pato ti lọkọlaya naa fi sin ọmọ wọn laaye ṣugbọn awọn kan sọ pe lẹẹkọọkan ọmọ naa maa n ni abuda agọ ara pe boya torii rẹ si ni wọn ṣe n gbimọ pẹlu babalawo lati pa a.

Iroyin sọ pe idajọ iku ni fun afurasi naa bi ile ẹjọ ba ri i pe o jẹbi ẹsun ti wan fi kan an labẹ iwe ofin ilẹ Ghana toripe afurasi naa lo mọọmọ fa iku ọmọ naa.

Iṣẹlẹ ki wọn maa pa ọmọ toriipe wọn gbagbọ o jẹ ọmọ ẹlẹmikẹmi ko wọpọ ni Ghana ayafi ẹẹkọọkan bii eleyii to si maa n fa idamu si ọkan awọn araalu atipe iwe ofin ọdun 1992 pese fun idaabo bo ẹmi eniyan.