Hausa, yoruba clash in Ogun: Bóyá Bàálẹ̀ tí wọ́n ní wọ́n dáná sun ló ṣá ìṣáná fúnrarẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ 'jẹnẹrétọ̀'

Ija igboro bẹ silẹ ni ilu Abekouta nipinlẹ Ogun laarin awọn ẹya Yoruba ati ẹya Hausa to n gbe ni adugbo Ọja Lafenwa ni Abeokuta, olu ilu ipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ owurọ ọjọ Aje ni ikọlu naa ṣẹlẹ ko to wa di ranto lọjọ Iṣẹgun eyi to fa ki wọn maa dana sun oniruuru ile itaja ti ọpọlọpọ eeyan si farapa nibẹ.
Alukoro Ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ṣalaye lori eto rẹdio kan nipinlẹ Ogun pe ootọ ni ija waye laarin arakunrin Hausa kan ati Yoruba kan ti iwadii si fidi rẹ mulẹ pe Yoruba ṣe Hausa ọhun léṣe.

"Nkan taa le pe ni ahesọ ọrọ lo da wahala Lafenwa silẹ, ohun toju wa ko to ka maa sọ pe o ṣẹlẹ". Alukoro Ọlọpaa na ni lojiji lawọn kan kan dede jade ti wọn n sọ pe Hausa ti wọn gbe lọ ileewosan ti Yoruba ṣeleṣe ti ku.
"Hausa na ko tii ku, ko sẹni kankan to ku, aye lo wa, tori mo wa nileewosan FMC ti wọn gbe e lọ". O ni ahesọ ọrọ lo fa a ti awọn Hausa ẹgbẹ rẹ fi gbera pe afi kawọn naa lọ gbẹsan lara Yoruba ọhun.
Iroyin to gbode kan sọ pe ọpọlọpọ dukia to to miliọnu ni wọn bajẹ latari ikọlu yii.
Ẹwẹ, Oyeyemi ni ọwọ ti tẹ eeyan meje lara awọn to da wahala yii silẹ ati pe awọn si n ṣewadii lọ. O ni gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa lawọn yoo ṣa pe.
"Atẹni to kọkọ bẹrẹ wahala to ṣe eeyan leṣe ati awọn to n farapamọ labẹ irọ pe Lagbaja ti ku ti wọn n fa wahala gbogbo wọn la o fi jofin".
O ni Seriki Hausa nipinlẹ naa to wa sibẹ lati wa petu saawọ gan wọn ṣe e leṣe gidi gan toun naa ti ba ara rẹ ni ileewosan to n gba itọju.

"Ahesọ kan naa tun wa lọ kaakiri pe wọn dana sun Baalẹ kan, Muyideen Akanni nibi kan, iwadii ti awa ṣe titi di asiko yii ko fihan pe wọn dana sun Baalẹ kankan".
"Ijamba ina ni awa ka jijona Baalẹ Muyideen si toripe gbogbo oju ferese ti awọn eeyan n pariwo pe ole gba wọle ni a yẹwo ti ko si wa ni ipo ibajẹ".
O ṣalaye pe boya Baalẹ ọhun lọ si ẹgbọ ẹrọ alupupu amunawa wọn, boya o si tun wa ṣa iṣana nibẹ ni ina ṣe bugbamu to ran mọ ẹrọ amuna wa ọhun.
O ni idi ni pe ko si aridaju tabi ijẹri ẹnikẹni to wa lati sọ pe eeyan kan lo kanlẹ lọ da ina sun Baalẹ ọhun lọsan gangan.
"Ati pe iyawo Baalẹ ọhun sọ fun wa pe oun kan dede gbọ ariwo nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ".
Alukoro Ọlọpaa ni Seriki ti n gba itọju bayii nileewosan Federal Medical Cetre, Idi-Aba.
Bakan naa lo ni awọn ti kawọ iṣẹlẹ naa ko bayii.
Olutaja kan to ṣoju rẹ koro kan sọ fun awọn oniroyin kan pe ohun to mu ki ija naa burẹkẹ sii ni pe wọn lero pe arakunrin Hausa ti wọn ṣeleṣe gidigan ti ku eyi lo si ni o mu inu bi awọn Hausa to n gbe nibẹ ti wọn fi tu sita ti wọn si n ba ọpọlọpọ dukia jẹ.
Amọṣa, Oyeyemi fi aridaju han pe lodi si ariwo ti awọn eeyan n pa kiri, ko si ẹmi kankan to ba iṣẹlẹ naa lọ,




















