Court sacks Ebonyi state governor: Iléẹjọ́ yọ gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi, igbákejì rẹ̀ nípò fún pípààrọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú

Oríṣun àwòrán, Ebonyi state government
Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja ti paṣẹ pe ki gomina ipinlẹ Ebonyi, David Umahi ati igbakeji rẹ, Ọmọwe Eric Kelechi Igwe o fi ipo silẹ.
Ile ẹjọ giga apapọ naa ni ọhun ni fun gomina Umahi ati igbakeji rẹ lati ṣi joko le aga gomina lẹyin ti wọn fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ si APC nigba to jẹ wi pe ẹṣin ati aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn gun wọle.
Onidajọ Iyang Ekwo ṣalaye ninu idajọ lọjọ Iṣẹgun pe niwọn igba ti wọn ti lee lọ si ẹgbẹ to padanu idibo gomina nipinlẹ naa ko si anfani fun wọn mọ labẹ ofin lati ṣi di ipo gomina mu rara.
O ni awọn mejeeji ko gbe awijare kalẹ tako ilana pe iye ibo to ba jade lasiko idibo kan jẹ ti ẹgbẹ oṣelu to ni awọn oludije.
- Timothy Adegoke: Raheem Adedoyin ní káwọn òṣìṣẹ́ Hòtẹ́ẹ̀lì òun fi Bíbélì búra pé wọ́n ò ní tú àṣírí
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Ademola Adeleke ti dìbò, wo bó ṣe ń lọ ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ́ táwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP Osun ti yapa láti yan ọmọ oyè
- Ẹ má bẹrù láti wọ ọkọ̀ BRT wa, kò séwu - Gómìnà Sanwo-Olu
Bawo lọrọ naa ṣe bẹrẹ?
Idajọ naa waye lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe ẹjọ pe ki gomina naa fi ipo silẹ pẹlu igbakeji rẹ.
Ile ẹjọ naa ni ohun to gbọngbọn tile ẹjọ naa mu gbọ ni bi olujẹjọ kẹta ati ikẹrin, iyẹn gomina Umahi ati igbakeji rẹ, Igwe ṣe fi ẹgbẹ oṣelu to gbe wọn wọle sipo silẹ.
O ni awijare ti awon olujẹjọ fi sita niwaju ile ẹjọ naa ko rinlẹ to lati gbe igbesẹ wọn lẹyin.
O wa fi kun un pe igbesẹ gomina naa ati igbakeji rẹ lee da iwe ofin orilẹ-ede Naijiria ru.
Ki wa ni yoo ṣẹlẹ bayii?
Ile ẹjọ naa ni aye yii ko gbọdọ ṣofo.
Nitori naa, Onidajọ Ekwo wa paṣẹ fun ẹajọ eleto idibo ni Niajiria, INEC lati dẹkun riri Umahi ati Igwe gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ebonyi ati Igbakeji rẹ.
Nigba to n tọka si abala okooleniigba ati ẹyọkan, section 221 iwe ofin Naijiria tọdun 1999, Onidajo Ekwo wa paṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP lati fi orukọ awọn ti yoo rọpo awọn mejeeji yii ranṣẹ si ajo INEC ki wọn le tun idibo tuntun ṣe.














