Àsìkò ti tó fún wa láti gba ìpínlẹ̀ Ọṣun padà lẹ́yìn ọdún kejìlá ti a tí ń se ẹgbẹ́ alátakò- Alága PDP Ọṣun

Alaga PDP Osun

Àsìkò ti tó fún wa láti gba ìpínlẹ̀ Ọṣun padà lẹ́yìn ọdún kejìlá ti a tí ń se ẹgbẹ́ alátakò- Alága PDP Ọṣun

Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, n'ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Sunday Biyi ti sọ̀rọ̀ soke nipa idibo Osun.

O fohun lede wi pe o ti to akoko fun ẹgbẹ oṣelu naa lati gun ori apere ijọba ipinlẹ Ọṣun, lẹyin ọdun mejila ti ẹgbẹ naa ti n ṣe alatako n'ipinlẹ naa.

Nibo ni Alaga ti sọ̀rọ̀ yii?

Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọ l'ọjọ Aje nilu Ọṣogbo saaju ẹto idibo abẹnu ẹgbẹ naa ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2022, Biyi ni alaafia ni ẹgbẹ oṣelu PDP wa n'ipinlẹ Ọṣun.

O ni bo tilẹ jẹ wi pe ẹgbẹ to n ṣe ijọba lọwọ n'ipinlẹ naa n lo awọn eeyan perete kan lati da omi alafia ẹgbẹ oṣelu naa ru sibẹ́ ko ni sewu loko.

Bakan naa lo ni ti igbimọ ẹgbẹ naa si ti gba gbogbo ọna lati pẹtu si irufẹ awọn ẹniyan bẹẹ lọkan, ṣugbọn wọn kọ eti ikun.

Honorebu ni eyi ko seyin pe wọn gbe iṣẹ fun wọn lati ita ni wi pe ki wọn lọ da omi alaafia ẹgbẹ oṣelu PDP ru.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Kini Honorebu naa tun sọ̀?

Alaga ẹgbẹ naa ni, "Ko si bi ẹ ṣe alọ, ko le ran wọn, wọn ko le gbọ. Bi o ṣe wa niyẹn, ṣugbọn awa ti tẹsiwaju, a dẹ ti gbaradi lati gba ijọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC n'ipinlẹ Ọṣun."

O tẹsiwaju wi pe awọn eniyan to n fi apa janu ko le ṣe idiwọ fun ẹgbẹ oṣelu naa ninu ilepa rẹ lati gba ijọba n'ipinlẹ Ọṣun.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Kini Honorebu so lori idibo to n bọ̀ naa?

Lori igbaradi fun eto idibo abẹnu ti yoo waye ninu ẹgbẹ oṣelu naa, Họnọrebu Biyi se alaye wi pe,

"Awọn amuṣẹṣe ẹgbẹ wa lo maa n da ọjọ ati akoko fun iru nnkan bi eleyii nitori awọn lo n bọ wa ṣe akoso rẹ.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

O tun salaye pe: Awọn ni wọn da ọjọ keje oṣu keta tẹlẹ, ki wọn to wa yii pada si ọjọ kejọ oṣu kẹta."

O fi kun ọrọ rẹ wi pe eto idibo abẹnu naa ti yoo waye ni gbagede iṣere nla ti ilu Oṣogbo, 'Oṣogbo Township Stadium' lọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2022 yoo lọ ni irọwọrọsẹ nitori awọn agbofinro ti ṣetan wamuwamu.

Gbogbo awọn ẹṣọ aabo oju popo, ileeṣẹ ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ ati awọn agbofinro mii ni wọn ti ṣetan lati daabo bo ẹmi ati dukiya awọn eeyan ni ibudo ti ibo naa yoo ti waye.

Eeyan mẹfa ọtọọtọ lo n dije du ipo ọmọ oye ninu eto idibo abẹnu ti ẹgbẹ ọṣelu PDP n'ipinlẹ Ọṣun.

Awọn naa ni: Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2018, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, Dr Akin Ogunbiyi, Họnọrebu Sanya Omirin, Alhaji Fatai Akinbade, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ati Dele Adeleke.

Họnọrebu Biyi parọwa si awọn ọmọ ẹgbẹ ọṣelu PDP ipinlẹ Ọṣun lati lọ si ibudo idibo pẹlu ọkan kan lai si rogbodiyan kankan, ki wọn ṣee ni irọwọrọsẹ, nitori awọn eeyan Ọṣun n reti ẹgbẹ PDP.

O ni ẹgbẹ naa ko fẹ ki ija ko waye ni ibi eto idibo naa, pẹlu alaye wi pe ibi ti igi ba wo si, ki onikaluku gba bẹẹ, ki wọn gbaruku ti ẹgbẹ naa ki wọn le tẹsiwaju lati gba ijọba lẹyin ọdun kejila ti wọn ti n foju han gẹgẹ bi i ẹgbẹ alatako.