Road Accident: Ìjàmbá ọkọ̀ tún gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́tàlá ní òpópónà márosẹ̀ Ilorin sí Ogbomoso

Tírélà tó jóná
Àkọlé àwòrán, Tírélà tó jóná

Kò dín ní ènìyaǹ mẹ́tàlá tó tún pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní òpópónà márosẹ̀ Ilorin sí Ogbomoso ní òwúrọ̀ yìí.

Agbẹnusọ ajọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara Ajayi Okasanmi tó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún ikọ̀ ìròyìn BBC ní àwọn ènìyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ jóná kọjá mímọ̀.

Okasanmi ní ní nǹkan bí aago méje ku ìṣẹ́jú díẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹta ọdún 2022 ni ọkọ̀ akérò Toyota Hummer kan àti tírélà tó kó sìmẹ́ǹtì forí sọra.

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo

Báwo ni ìjàmbá náà ṣe wáyé?

Ó ṣàlàyé pé bọ́ọ̀sì Hummer náà tó ń bọ̀ láti Eko ló ń lọ sí ìpínlẹ̀ Katsina ṣùgbọ́n tó gba ọ̀nà tí kìí ṣe tirẹ̀ níbi tó ti lọ forí sọ ọkọ̀ ńlá náà tó ń bọ̀ láti árìwá lọ sí Eko.

Okasanmi fi kun pé ènìyàn mẹ́tàlá nínú àwọn tó wà nínú bọ́ọ̀sì ló jẹ́ Ọlọ́run ní pè tí àwọn mìíràn sì farapa.

Àjọ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ àti pé àwọn ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ìkọ́ni UITH fún ìtọ́jú.

Bákan náà ni wọn ti gbé àwọn òkú náà lọ sí ilé ìgbókùpamọ́sí UITH.

Lílòdì sí òfin ojú pópó ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn ni ìjàmbá ọkọ̀ wáyé ní ilorin

O kere tan, eeyan mẹsan an ti jade laye ninu ijamba ọkọ kan ni ipinlẹ Kwara.

Ijamba naa waye laarọ ọjọ Isinmi niwaju papakọ ofurufu ilu Ilorin to wa loju ọna Ilorin si Eyenkorin.

Adari ileeṣẹ to n ri si irinkerindo oju popo ni Kwara, Jonathan Owoade sọ pe ọkọ akero Toyota Hiace ati ọkọ Toyota Corolla kan ni ọrọ naa kan, nigba ti eeyan mẹtadinlogun fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun.

Oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin pe ọkọ mejeji fori ṣo ara wọn lasiko ti ọkọ ayọkẹlẹ Toyota to n bọ lati inu papakọ ofurufu fori sọ ọkọ Toyota Hiace akero to n rinrinajọ lọ siluu Eko, lẹyin naa ni ina sọ.

Iroyin ni awọn mẹsan an to jade laye ninu ijamba naa jo kọja mimọ, wọn si ti ko oku wọn lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣẹgun ti fasiti Ilorin.

Yatọ si awọn mẹsan an to ku yii, awọn marun un mi tun farapa, amọ wọn ti n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Ẹwẹ, awọn okunrin mẹta mii to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa moribọ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, adari FRSC ni Kwara sọ pe ijamba naa iba ma ti waye ti ko ba si ere asaju loju popo.

O si tun rọ awọn awakọ loju popo lati ṣọra fun ere asapajude.

Owoade tun kilọ fun awọn awakọ lati ṣọra fun kiko epo bẹntiro pamọ sinu ọkọ wọn.

Lẹyin naa lo ba ẹbi awọn to ba ijamba naa lọ kẹdun.

O tun sọ pe FRSC yoo ṣiṣẹ takun-takun lati ri daju pe irufẹ ijamba bẹẹ ko waye mọ.