Russia and Ukraine Update: Iléeṣẹ́ Meta ní òun ti fààyè gba ìpè fún ìwà ipá sí ààrẹ àti ọmọ ogun Russia, orílẹ̀èdè náà yarí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileesẹ to n se ọfintoto awọn oju opo ayelujara lorilẹede Russia, Roskomnadzor, ti kede pe oun yoo gbe idi da oju opo Instagram nitori ipe fun iwa ipa sawọn ọmọ ologun orilẹede naa.
Ẹni to ni oju opo Instagram naa lo kede pe oun yoo gba awọn onibara oun laaye lawọn orilẹede kan lati pe fun iwa ipa si aarẹ ilẹ Russia, Vladimir Putin atawọn ọmọ ogun rẹ.
Bakan naa lo salaye pe oun yoo faaye gba awọn iroyin to nii se pẹlu ipe fun iku awọn ologun Russia, eyi to tako ilana amulo oju opo ayelujara ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Portable Zazzu pariwo pe wọ́n ti dá ọjọ́ méje pé òun yóò kú
- Ohun tó bá kàn ìlú Ibadan, kàn mí - Gómìnà Ganduje
- Tẹ̀gbọ́n tàbúrò jí ọmọ ará àdúgbò gbé láti gbowó, àmọ́ wọn fún ní òògùn eku jẹ
- "Èèdì àti ogun ayé ni awọn èèyàn n rò pé ó mú mi bí ìbejì ní ìgbà mẹ́fà"
- Ọjọ́ Ajé la bẹ̀rẹ̀ ìpè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation padà - Akintoye
- Malami pahùndà lórí ọ̀rọ̀ Kyari, ó ní kò jẹbi ẹ̀sùn kíkówó pamọ́
Amọ o yan pe oun ko ni fi aaye gba ipe fun iwa ipa sawọn araalu lorilẹede Russia.
Amọ nigba to n fesi si ikede ẹni to ni oju opo Meta, ti Instagram wa lara rẹ, ijọba Russia ke silẹ Amẹrika lati da awọn akọni to ni awọn oju opo ayelujara lẹkun irekọja wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lọjọ Ẹti si ni ileesẹ agbefọba ni Russia kede pe ki wọn bẹrẹ iwadi lori ileesẹ Meta, to si n tọka si iwa ti Instagram hu naa.
Lọjọ Kẹrin osu Kẹta si ni Roskomnadzor ti kede pe oun ti gbegi dina oju opo Facebook lorilẹede Russia nitori iwa idẹyẹsi to n hu sawọn ileesẹ iroyin ni Russia.
Ileesẹ Meta yii naa lo si ni Facebook, Instagram ati WhatsApp.
Amọ orilẹede Russia ko ti fofin de lilo oju opo WhatsApp nitori wọn si n fi ọrioyin ransẹ dipo isẹ ipese idẹrun.

Àkọ́dá oró...Russia fì ìbínú gbèsan lára àwọn tó gbégi dínà òwò pẹ̀lú àwọn eèyàn Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orileede Russia ti bẹrẹ si ni gbẹsan pada lori awọn ijiya ọrọ aje tawọn orileede ilẹ Yuroopu n gbe le.
Ijiya ti wọn la kalẹ yi ko si sẹyin bi Russia ti se gbogun ti orileede Ukraine.
Nitori naa Russia ti gbẹsẹ le tita awọn nkan eelo kan fawọn to ni awọn naa ko ni ra nkan lati ọdọ rẹ tabi ti wọn gbe ijiya ọrọ aje miran le ilẹ naa.
Igbese wo ni Russia n gbe bayii?
Ninu nkan ti Russia fẹ se bayi ni pe wọn ko ni ta nkankan to ba ni se pẹlu eto ibaraẹnisọrọ(Telecoms) eto ilera, ọkọ tita,eto ọrọ aje, tita awọn irinsẹ amunawa ati nkan mii bi igi gẹdu.
Ileesẹ eto ọrọ aje Russia tẹsiwaju pe awọn yoo tun gbẹsẹ le awọn ọkọ oju omi orileede mi lati wọ ilẹ wọn.
Russia sọ pe ''esi to yẹ si awọn ijiya ti wọn gbe le wa lawọn igbesẹ yi''
Bakan naa ni ileesẹ yi sọ pe ijiya tawọn naa gbe kalẹ lori awọn orileede to foju oro han
Russia wa ni ''ibamu lati ri pe gbogbo ẹka ọrọ aje ilẹ wa ni ko si idiwọ kankan nibẹ''
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Àwọn gómìnà 'yahooyahoo' ní APC ló ń ti Buni láti da ojú ètò ìdìbò adarí ẹgbẹ́ bolẹ̀ - Gómìnà Rotimi Akeredolu
- Ìrírí akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Ireland kan rèé tó ṣì ń gbìyànjú ọ̀nà àti sá àsálà kúrò ní Ukraine
- Lẹ́yìn tí wọ́n gba ipò alága NURTW lọ́wọ́ rẹ̀, MC Oluomo yapá kúró ní NURTW
- Ìrírí tí Ilana Omo Oodua àti Sunday Igboho rí lósù mẹ́fà yìí tí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ síi- Ojogbon Banji Akintoye
Awọn ijọba lawọn orileede Yuroopu ti gbe awọn ijiy orisirisi le Russia paapa nipa rira epo rọbi,ati lori awọn baba olowo ti wọn ba ri pe wọn ni ajọsepọ pẹlu aarẹ Russia, Vladimir Putin.
O kere tan orileede mejidinlaadọta ni ijiya ti Russia gbe kalẹ yi yoo kan ninu wọn si lawọn orileede ajọ Yuroopu to fi mọ ilẹ Amẹrika.
Olootu ijọba Russia Mikhail Mishustin sọ pe awọn yoo gbẹsẹ le tita awọn ọja ti o n jade lati ileesẹ tawọn orileede mii ni to wa ni Russia .
Awọn nkan tawọn ileesẹ wọn yi n gbe jade ninu rẹ la ti ri ọkọ,reluwe ati kọntena ti wọn fi n ko ẹru.
Igbesẹ yi n waye lẹyin ti aarẹ tẹlẹ Dmitry Medvedev kilọ pe awọn nkan ini ileesẹ orileede mii to wa ni Russia ti wọn sa kuro seese ko di nkan ti Russia le gbẹsẹ le.
Lara awọn ileesẹ to n sa witiwiti kuro ni Russia tabi ti wọn ko doko owo nibẹ mọ ni awọn to n wa kusa bi Caterpillar and Rio Tinto, Starbucks, Sony, Unilever ati Goldman Sachs.
Lọjọru Moscow buwọlu ofin eyi ti wọn fi bẹrẹ igbesẹ bi wọn yoo se gba awọn dukia eyikeyi ileesẹ to ba kogba kuro ni Russia.
Kini o wa ninu atejade Medvedev?
Ninu atẹjade kan lỌjọbọ, arakunrin Medvedev sọ pe ''ijọba Russia n sisẹ lori awọn igbesẹ kan to fi mọ gbigba dukia awọn ileesẹ orileede mii to wa ni Russia fun ijọba ilẹ naa''
''Awọn ileesẹ orileede mii ni lati mọ pe pipada si ọja wa lati wa sowo yoo nira.''
O naka aleebu si awọn ileesẹ ilẹ okeere fun bi wọn ti se n da iporuru ọkan silẹ fawọn araalu ilẹ naa to seeese ki wọn padanu ọna ijẹ ati mu wọn.
Gẹgẹ bi akọsilẹ taa ri laipẹ yi, Russia ni orileede ikọkandilogun lori agbelewọn awọn to n ba ilẹ Gẹẹsi sowo pọ.
Iye owo ọrọ aje laarin awọn mejeeji lapapọ to £15.9bn.



















