Áńkọ́fù ológun kéré fún ọwọ́ mi àmọ́ wọ́n fi okùn dì mí kúrò nílé lọ sí bárékè Odogbo
Ni ọdun to kọja ni awọn ẹbi gbajumọ asaaju awakọ ero kan nipinlẹ Oyo, Alhaji Azeez Moruff ti ọpọ eeyan mọ si Tula Oyo, kigbe tọ BBC Yoruba wa pe awọn ologun kan ti wa di baba awọn ni apanyaka lọ.
Amọ lẹyin osu mẹta, Tula Oyo gba idande kuro ni ahamọ ologun ati DSS, lẹyin ti ile ẹjọ ni ki wọn fi silẹ.
Bakan naa ni ile ẹjọ tun ni ki wọn san owo gba ma binu ọgọrun miliọnu naira fun ọkunrin naa nitori bi wọn se ba lorukọ jẹ.
- "Ẹ bá wa tú Tula Oyo sílẹ̀, Bàbá wa kò mọ ohunkohun nípa bí wọn ṣe já ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo"
- Tówẹ́ẹ̀lì ni bàbá mi ró mọ́ ìdí nígbà tí àwọn sọ́jà wọlé mu lọ - Ọmọ Akintunde
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- DSS ní kí n di ológbò bíi Sunday Igboho, ojú mi rí tó ní àhámọ́ DSS l'Abuja- Ifasooto
- Mo gbọ́ pé babaláwo mẹ́ta ló tẹ̀lé àwọn DSS lọ sí ilé Sunday Igboho- Gani Adams
Nibayii, Tula Oyo ti wa ba BBC Yoruba sọrọ lori irinajo rẹ si ileesẹ ologun ati DSS, ohun ti oju rẹ ri lọwọ wọn ati bawọn mọlẹbi rẹ se sugba rẹ.
Nọmba ipe Sunday Igboho lo gbe mi de ahamọ DSS fun osu mẹta.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Tula Oyo ni towẹ́li lasan ni oun lọ mọdi ni ọjọ ti awọn ologun wa gbe oun.
O ni ọpẹlọpẹ ẹbẹ awọn ara adugbo ti wọn bẹ awọn ologun naa lo jẹ ki wọn gba pe ki oun wọ asọ si ọrun.
O ni awọn ologun naa, ti wọn le ni ogoji, ni ankọọfu ti wọn mu dani kere lati gba ọwọ oun amọ se ni wọn lo okun lati fi di oun lọ si agọ wọn.
Asaaju ẹgbẹ ọlọkọ ero tẹlẹ nipinlẹ Oyo naa fikun pe bareke ologun to wa ni Odogbo nilu Ibadan, ti wọn gbe oun lọ ni wọn ti ka ẹsun mẹta si oun lẹsẹ.
Awọn ẹsun mẹta tawọn ologun ati DSS ka si mi lọrun ree, ti wọn se mu mi:
Tula Oyo salaye pe lara awọn ẹsun ti wọn ka si oun lọrun ni pe oun ni nnkan se pẹlu ọgba ẹwọn Abolongo ti wọn ja nilu Oyo, ti awọn ẹlẹwọn fi raye sa lọ.
Ẹsun keji ni pe oun lọwọ ninu iwọde Endsars ti awọn ọdọ se eyi to milẹ gidi.
Ẹsun kẹta ni pe oun ni ajọsepọ pẹlu oloye Sunday Igboho nitori pe nọmba ipe rẹ wa lori foonu oun.
Amọ o ni oun salaye pe awọn ẹsun meji akọkọ ni oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ, ti oun si ni o ti le ni ọdun mẹẹdọgbọn ti oun ti mọ Igboho.
Ọrọ pọ ti Tula Oyo sọ nipa bi awọn ologun se gbe lọ si ahamọ DSS nilu Abuja ati ohun ti oju rẹ ri nibẹ pẹlu bo se gba idande lẹyin osu mẹta.
Ẹkunrẹrẹ awọn alaye rẹ si wa ninu fidio yii, ẹ woo.





