AFCON 2019: Idíje Egypt ati Zimbabwe, ọ̀rọ̀ kọ sísọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Idije AFCON fawọn agbabọọlu ilẹ̀ Adulawọ lo bẹrẹ ni ana ni orilẹ-ede Egypt.
Ikọ agbabọọlu Egypt ati Zimbabwe ni wọn koju ara wọn ninu idije iṣide ni Cairo.
Ninu idije naa ni Egypt ti na Zimbabwe pẹlu ami ayo kan si odo nipa kọju si mi koo gba a sile.
Awọn orilẹ-ede mẹrinlelogun ni wọn jọ maa woju ara wọn ninu idije AFCON tọdun 2019 fun igba akọkọ.
Opolopo eeyan ni wọn ni eto iṣide naa dun daadaa nibi ti Femi Kuti atawọn olorin miran ti da awọn eniyan lara ya.
Mahmoud Trezeguet lo gba ami ayo kan ṣoṣo naa si awọn ikọ Zimbabwe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu Liverpool, Mo Salah fẹẹ gba goolu keji wọle sawọn ṣugbọn Edmore Sibanda to jẹ aṣọle Zimbabwe sọ pe oni kọ.
Awọn agbabọọlu Zimbabwe bii Ovidy Karuru naa gbiyanju ṣugbọn ẹ̀pa ko boro titi idije naa fi pari.
Eyi kọ wa pé ko si ohun daradara to wu ilẹ Adulawọ lati ṣe ti a ko le ṣe.
Eto iṣide idije naa ni awọn eniyan gba pé o dun bii ti iṣide ife ẹyẹ agbaye Russia 2018
O fẹrẹ tó ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin ero ti wọn peju si papa iṣere ni Cairo wa wo idije iṣide naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹkọ pataki ti awọn eniyan n sọ ni pe ki ikọ kankan ma gbojule ẹnikan ṣoṣo fun ogo idije wọn.
Opolopo lo fi Mohammed Salah ṣe apẹẹrẹ ninu idije yii nitori oun kọ lo pada gbogo fun Egypt.
Ẹnikẹni lo le jẹ koriya fun awọn akẹgbẹ rẹ lasiko idije.
Awọn eniyan ni ki Naijiria fi ti Egypt kẹkọọ pé ko si ẹni ti ko le jẹ koriya fun awọn akẹgbẹ rẹ lasiko idije bii ti Sallah ti Liverpool.
Nitootọ ni ariwo ero pọ fun Mohamed Salah to n gba bọọlu fun Liverpool ṣugbọn o kan gbiyanju ti ara rẹ lasan ni.
ọpọlọpọ gba pe idije Egypt to ku lẹyin tun maa dun ju eyi lọ pẹlu ero pe Salah a da bira pẹlu bọọlu.














