AFCON 2019: Báwo ni ìdíje Super Eagles àkọ́kọ́ yóò ṣe lọ?

Oríṣun àwòrán, Charlotte Wilson/Offside
Ami ayo kan si odo ni ikọ agbabọọlu Super Eagles ti orilẹede Naijiria fi ki ikọ agbabọọlu Burundi kaabọ sinu idije ife ilẹ Afrika, Afcon 2019 to n lọ lọwọ ni orilẹede Egypt.
Idije naa to waye ni ilu Alexandria l'orilẹede Egypt ni idije akọkọ fun orilẹede mejeeji.
Odion Ighalo lo gba bọọlu kan ṣoṣo ọhun wọle fun Super Eagles nigba ti idije na wọ iṣẹju mejidinlọgọrin.
Bi Super Eagles ṣe bori yii ti mu ki o ṣeesẹ fun wọn lati wa ni oke tente ni aarin awọn ti wọn jọ wa ni isọri kan naa.
Ọmi odo ni ikọ mejeeji gba ni abala akọkọ idije naa.
Ẹẹmeji ọtọọtọ ni ikọ Super Eagles paarọ agbabọọlu; Awaziem lo kọkọ rọpo Shehu ni iṣẹju mọkanlelogoji, ti Mohammed Musa na si wọle sori papa lati rọpo Mikel Obi iṣẹju mẹtadinlaadọta ni idije naa.

Idije ife ẹyẹ tilẹ Adulawọ laarin awọn agbabọọlu alafẹsẹgba ti bẹrẹ ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa.
Orilẹ-ede Egypt lo n gbalejo awọn orilẹ-ede mẹrinlelogun ti wọn jọ n koju ara wọn ki ẹnikan to gba ife ẹyẹ lọ.
Egypt ati akẹgbẹ wọn ni Zimbabwe ni wọn jọ figagbaga ti wọn ṣide idije naa ni ana.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹ-ede Egypt gba ami ayo bọọlu kan sáwọ̀n Zimbabwe ti wọn ko si ri da pada.
Loni ni Naijiria yoo maa gbena woju awọn akẹgbẹ wọn lati Burundi.
Wo ohun tó yẹ ki o mọ̀ nípa Burundi:
Swallow ti Burundi ni wọn n pe orukọ inagijẹ ẹgbẹ agbabọọlu to n gba fun orilẹ-ede Burundi.
Ikọ yii ko pegede ri lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye.
Egbẹ agbabọọlu Burundi ko jade ṣoju orilẹ-ede wọn ri laarin 1930 si 1990 ti idije ife ẹyẹ agbaye ti bẹrẹ.
Ọdun 1994 lo ku diẹ ki ikọ agbabọọlu Burundi yege lati kopa ninu idije ife ẹyẹ Adulawọ.

Sugbọn orilẹ-ede Guinea re wọn lẹpa ti ko fi jẹ ki wọn le yege.

Kọju si mi ki n gbaa sile ni Guinea fi na Burundi lọdun 1994.
Odun 2019 ni Burundi ba oogun eewọ máleèkópa wọn jẹ ti wọn si pegede ninu idije kikopa.
Igba akọkọ ni yii ti wọn maa yege lati dije ninu ife ẹfẹ ẹyẹ Afrika.
Lọdun 1998 ati 2002 ni Burundi yẹba ninu idije lẹyin ti wọn gbiyanju lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye.
Ọdun 2006, 2010, 2014, 2018 ni wọn ko ti yege lati kopa rara ninu idije ife ẹyẹ agbaye.
Awọn bii Abdul Karim Niyizigimana to jẹ adiẹyin ile mu naa ni awọn ti wa ni sẹpẹ lati gbogo fun Burundi loni.
Kikopa ninu AFCON latẹyinwa:
Orilẹ-ede Burundi ko kopa ri lati ọdun 1957 ti AFCON ti bẹrẹ titi di ọdun 1974.
Wọn kopa ninu idije lọdun 1976 ati 1978 ṣugbọn wọn ko yege.
Wọn yọ ara wọn kuro ninu idije lọdun 1980 ati lọdun 1998.
Odun 2019 yii ni igba akọkọ ti Burundi a yege lati kopa ninu idije ifẹ ẹyẹ Adulawọ AFCON.

















