Seyi Makinde: Ìrírí, ọ̀gbọ́n àti ìmọ̀ ìgbìmọ̀ yìí yóò ṣèrànwọ́ fún ìjọba mi

Seyi Makinde ati awọn ọmọ igbimọ olugbaninimọ̀ran

Oríṣun àwòrán, Oyo state Government

Igbin tẹnu mọ igi, o gun, ni Gomina Seyi Makinde fi ifilọlẹ igbimọ olugbaninimọran to kede laipẹ yii se.

Ni owurọ ọjọ Ẹti, ni Gomina Makinde se ifilọlẹ igbimọ ẹlẹnu mẹwa naa to kede laipẹ yii, ryi ti Sẹnetọ Hosea Ayọọla Agboọla ko sodi.

Nigba to n se ifilọlẹ igbimọ naa, Makinde ni afojusun agbekalẹ igbimọ naa ni lati se afikun imọ ati iriri awọn asaaju ijọba oun, nipa gbigbe imọran pataki kalẹ fun ijọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Makinde ẹni to ni ti ko si ba si igi lẹyin ọgba, ọgba yoo wo, wa tọka si pe awọn ileesẹ nla nla n se aseyọri nitori igbimọ olugbaninimọran ti wọn gbe kalẹ nibẹ ni.

O fikun pe o se pataki kawọn ki ijọba oun ni awọn eeyan to ni ọgbọn, oye ati iriri ni gbogbo ẹka igbe aye ọmọniyan, ti wọn yoo maa kopa ninu eto akoso ipinlẹ Ọyọ.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn ọmọ igbimọ olugbaninimọran naa, alaga igbimọ naa, Sẹnetọ Agboọla seleri pe igbimọ naa yoo maa gbe imọran kalẹ loore koore lati mu ki ipese isejọba rere tẹsiwaju ni ipinlẹ Ọyọ.

Lara awọn ọmọ igbimọ naa ni Monsurat Sunmọnu, Mulikat Adeola Akande, Bọlaji Ayọrinde, Samson Ọlaoye, ati Sarafadeen Abiọdun Alli.

Àkọlé fídíò, Florida: Ọ̀ọ̀nì àléègbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

Sugbọn Sarafadeen Alli ko yọju sibi ibura naa.