Seyi Makinde: Àwọn ọba yoo ko ipa pataki lati gbogun ti aabo to mẹhẹ

Oríṣun àwòrán, Google
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti ni, ijọba oun yoo lo awọn ọba alaye ni agbeegbe kọọkan lati mu ibugbooro ba eto aabo ni ipinlẹ naa.
Gomina Makinde, to sọ ọrọ yii ni ibi ayẹyẹ ọjọ ibi Olugbọn ti Orile Igbon, Ọba Francis Alao, tun sọ wipe eto aabo wa lara awọn ohun ti isejọba oun duro fun.
O fikun wi pe, loore koore ni oun yoo ma a kan si awọn ọba naa, lati fun oun ni imọran ati ijiroro lori ọna abayọ si ipenija eto aabo.
Gomina ipinlẹ Ọyọ naa fikun pe, awọn ipo to jẹ gboogi ni isejọba oun ni awọn ọba naa yoo ti kopa fun ilọsiwaju ipinlẹ naa.









