Agbekoya Protest: Kò sí àtúnṣe òfin 1999, kò sí ìbò ní 2023

Awọn agbẹkọya to n se iwọde

Ẹgbẹ Agbekoya nilẹ Yoruba ti kede pe oun ti setan lati koju ijọba, ti ko ba dahun awọn ibeere ti awọn n fẹ.

Asaaju ẹgbẹ Agbekoya, Oloye Kamorudeen Okikiola lo fi ọwọ sọya bẹẹ fun BBC Yoruba lasiko iwọde wọn to waye lọjọbọ.

Iwọde naa si lo gbe wọn de aafin Olubadan tilu Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunnisọ Kinni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Okikiola ni ijọba ko le da Agbekoya mu ti awọn ba jade tan, ti ijọba ba si ta tan pẹlu awọn.

Awọn agbẹkọya to n se iwọde

Atunto Naijiria ati atunse ofin gbọdọ waye ka to le dibo ni 2023:

Nigba to n sọrọ lori eto idibo gbogbo gboo ti yoo waye lọdun 2023, asaaju Agbekoya ni eto atunto ati atunse ofin ilẹ wa gbọdọ waye saaju eto idibo naa.

"Iwe Ofin ti awọn ologun gbe kalẹ lọdun 1999 la n lo, a nilo lati se agbekalẹ iwe ofin tuntun saaju ibo 2023, bẹẹ ni a lko fẹ pada lo ofin ti wọn gbe kalẹ laye Awolowo.

Bakan naa ni atunto orilẹede Naijiria gbọdọ waye ka to le dibo lọdun 2023 nitori a ko lee maa fi ara da mọ pe ki wọn maa gbe awọn ẹya kan gori omiran.

Bi ijọba ko ba wa se atunse ofin ilẹ wa ati atunto Naijiria, a jẹ pe ko ni si ibo lọdun 2023 nuu."

Ẹ fi Sunday Igboho silẹ, bẹẹ se fi Boko Haram silẹ:

Ẹgbẹ Agbekoya tun ke si ijọba apapọ Naijiria pe ko sanna bi asaaju ajijagbara Yoruba Nation, Sunday Igboho yoo se gba idande ni ọgba ẹwọn to wa.

Agbekoya ni Sunday Igboho ko ni ẹsẹ kankan lọrun, to fi yẹ ki wọn fi si ahamọ ọgba ẹwọn, nitori ominira ilẹ Yoruba lo n ja fun.

"A n ke si ijọba Naijiria ati ti Benin pe ki wọn pawọpọ tu Sunday Igboho silẹ ni ọgba ẹwọn Cotonou to wa.

Awọn ijọba orilẹede mejeeji lo panusọ fi Igboho si ahamọ, awọn naa si ni ki wn fi silẹ nitori kii se apaayan tabi gbọmọ-gbọmọ.

Ijọba Buhari ti fi gbogbo Yoruba si ahamọ pẹlu bo se gbe Sunday Igboho, a ko si ni dakẹ.

Bakan naa ni wọn ti sọ awọn ọba ilẹ Yoruba si apo wọn, ti wọn ko si le sọ otitọ ọrọ mọ

Yoo si dara ki wọn tu Igboho silẹ, ka maa baa jade tan fun wọn nitori awa ko bẹru wọn.

Agbara wa, oogun si wa pẹlu, a ko si ni fẹ ko di ariwo ki ijọba to da wa lohun."

Agbekoya tun wa n rọ ijọba lati wa ojuse gboogi fawọn oriade ninu isejọba, ki ohun gbogbo le tuba tusẹ.

Awọn agbẹkọya to n se iwọde

Ẹ mase gbe igbesẹ lati yọ owo iranwọ kuro lori epo Bẹntiroolu:

Wayi o, Ẹgbẹ Agbekoya tun ti ke si ijọba apapọ pe ko mase tiraka lati yọ owo iranwọ kuro lori owo epo bẹntiroolu.

Wọn ni inira nla ni eyi yoo ko ba araalu, nitori ebi wa nita tẹlẹ.

Wọn wa gba ijọba nimọran lati wa ọna ti ara yoo fi dẹ araalu nitori ilu kan gogo lasiko yii.

Ẹgbẹ Agbekoya wa n ke sawọn onisẹ ibi bii apaayan, agbebọn, adigunjale, ajinigbe ati bẹẹ bẹẹ lọ pe ki wọn kuro nilẹ Yoruba nitori Agbekoya ti jade.

Amin iyasọtọ kan

Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ fi Sunday Igboho sílẹ̀, Agbekoya yarí

Awọn agbẹkọya to n se iwọde

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ẹgbẹ Agbekoya jakejado ilẹ Yoruba ti bẹrẹ iwọde alagbara lati beere fun itusilẹ gbajugbaja asaaju ikọ Yoruba Nation, Sunday Igboho, to si tun n beere awọn nnkan miran lọwọ ijọba.

Igboho lo ti wa ni ọgba ẹwọn nilu Cotonou lorilẹede Benin nigba ti wọn mu ni papakọ ofurufu ni Cotonou si ahamọ lasiko to n lọ silẹ Germany.

Awọn agbẹkọya naa, ti wọn ya sigboro ilu Ibadan, ni iwọde wọn gberasọ ni gbọngan Mapo, ti wọn si n yide kiri ilu Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti ẹgbẹ Agbekoya fi sita lọjọbọ lẹyin ipade wọn, saaju iwọde naa lo n sisọ loju rẹ pe asiko ti to fun ijọba apapọ baii lati tu eekannna lẹyin ọrun Igboho nitori ko ni ẹsẹ lọrun.

Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ Agbekoya lagbaye, Oloye Kamorudeen Okikiola salaye pe ẹgbẹ naa ti setan lati maa ja fun iran Yoruba, ko si daabo bo lọwọ awọn iwa ọdaran gbogbo.

Awọn agbẹkọya to n se iwọde

Okikiola mẹnuba ọpọ ohun ti ẹgbẹ agbekoya n se iwọde le lori, ti wọn si n fẹ ki ijọba se atunse si.

Lara awọn ohun ti ẹgbẹ Agbekoya si n fẹ ree:

  • Idande fun asaaju ajijagbara Yoruba Nation, Oloye Sunday Igboho lai fi falẹ rara
  • Ebi n bẹ ni Naijiria, ijọba apapọ ko si gbọdọ yọwọ kuro ninu owo iranwọ lori epo pẹntiroolu lati dena ọpọ inira ti igbesẹ naa le mu ba ara ilu
  • Awọn ọdọ ko ni isẹ oojọ lọwọ bi o tilẹ jẹ pe wọn ka iwe de ibi to ni apẹẹrẹ, ti ọrọ aje to dagun ko si jẹ ki awọn olookowo ati onisẹ ọwọ ri ti aje se
  • Aifararọ eto aabo nilo amojuto kiakia nitori iwa ijinigbe, igbesunmọmi, ipaniyan laibikita lati ọwọ awọn darandaran, idigunjale ati bẹẹ bẹẹ lọ ti di tọrọ fọn kale
  • Agbekalẹ igbimọ eleto aabo alajumọse ti yoo jẹ tawọn ologun, ọlọpaa, Civil Defence, DSS, Agbekoya, OPC, Ọdẹ Asọludẹrọ ati Fijilante
  • Atunse awọn oju popo to wa nilẹ Yoruba boya ni aarin ilu ni abi lawọn agbegbe igberiko nitori eyi yoo mu ki ounjẹ pọ yanturu laarin ilu ni owo pọọku
  • Fifun awọn ọba alade nilẹ Yoruba ni ojuse gboogi lati se ninu iwe ofin ilẹ wa
  • Aabo fun awọn agbẹ ninu oko ati gbigbaruku mọ isẹ ọgbin.
Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Atẹjade naa, ti alukoro ẹgbẹ Agbekoya, Olatunji Bandele fọwọ si tun wa fi ewe ọmọ mọ awọn agbofinro leti lati mase ti ọrọ ẹlẹyamẹya bọ eto aabo Naijiria nitori eyi lewu pupọ.

Lọwọ lọwọ bayii, awọn Agbekoya ti n se iwọde nilu Ibadan, bo ba si se n lọ, laa maa mu wa fun yin.