Ilegal Road Blocks in Nigeria: Gbogbo ọlọ́pàá tó ń gbégidínà lọ́nà àìtọ́, ẹ yọ wọ́n kúrò

Oríṣun àwòrán, Others
Ile Igbimọ Asofin ni Naijiria ti paṣẹ fun Ọga Agba Ọlọpaa lati yọ gbogbo gbigbe igi dina lọna aitọ kaakiri orilẹede Naijiria.
Eyi ko ṣẹyin bi ọmọ ile aṣofin lati ipinlẹ Imo, Ifeanyi Momah ṣe ke gbajare sita pe awọn oju popo yii n da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ, to si n fa ijamba ọkọ to gbẹmi awọn eniyan.
Ninu ọrọ rẹ, Momah ni ijọba gbọdọ ṣe iwadii ni kiakia nipa igbegidina awọn opopona to mu ẹmi awọn eniyan lọ ni opopona Owerri-Onitsha.
- Mo fún òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà di December 18 láti fi ipò tó wà sílẹ̀ - Gómìnà Fayemi
- Bí àdúrà ọjọ́ kẹjọ àti ayẹyẹ òkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé
- Kókó méje tó wà nínú ‘White Paper’ ìjọba Eko lórí àbọ̀ ìwádìí ìwọ́de EndSARS
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí méje tó ń pa èèyàn ṣe ètùtù ọlà l‘Ogun
- 'Oṣù mẹ́sàn-án ni wọ́n fi jí mi gbé tí wọ́n ń fipá bá mi lòpọ̀ títí tó fi di oyún'
O ni arin opopona ni awọn ọlọpaa gbe igi dena si eleyii to jasi iku awakọ tirela kan ati oṣiṣẹ rẹ, to fi mọ awọn to wa ninu ọkọ akero to le ni mẹwa.
Ọmọ Ile Igbimọ Aṣofin naa ni iye awọn to ku ninu iṣẹlẹ naa ko din ni mọkanlelogoji.

Oríṣun àwòrán, AFP
''Ni Ojọ Satide, Ọgbọnjọ Osu Karun, ọdun to kọja ni awọn ọlọpaa gbegidi opopona agbegbe Ihiala, to si jasi iku ọpọlọpọ eniyan ninu ijamba ọkọ naa''
''Kini igbegidina n wa laarin ọja, ileewe ati ileeṣẹ nibi ti ọpọlọpọ ero wa, ti ko si ni iṣẹ kan pato ti wọn n ṣe fun awọn eniyan.''
Lasiko to n fesi, Ile Igbimọ Aṣofin fi ontẹ lu u ti wọn si paṣẹ fun Ọga Agba Ọlọpaa lati paṣẹ fun kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Anambra lati y awọn ojuko igbegidina ti ko ba ofin mu.















