Ogun Ritualist: Wo orúkọ ti àwọn agbénipa ǹ pe ẹ̀yà ara èèyàn tí wọn ń fi ṣowó

Oríṣun àwòrán, Others
Asiri awọn afurasi agbenipa se owo meje kan ti tu sọwọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Ogun, Abimbola Oyeyemi fisita lo sisọ loju ọrọ yii.
Orukọ awọn afurasi afinisetutuọla naa ni Lekan Oladipupo, ẹni ọdun mejidinlogoji to n gbe ni abule Sotan ati Sulaiman Aremu, ẹni ọgbọn ọdun to n gbe ni adugbo Imala Elega nilu Abeokuta.
- 'Oṣù mẹ́sàn-án ni wọ́n fi jí mi gbé tí wọ́n ń fipá bá mi lòpọ̀ títí tó fi di oyún'
- Obìnrin ẹni ọdún 28 kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ariwo sọ!
- Bimbo Oshin Ṣàlàyé lórí bí ọkọ rẹ ṣe kú lẹ́yìn ìjáde opó
- Wọ́n yọ ẹ̀yà ara màmá wa tí wọn pa ní ṣọ́ọ́ṣì Deeper lọ - Ẹbí pariwo
- Ẹ̀mí Ọlọ́pàá àti ọ́ọ́físà àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó bó níbi idigunjale Banki tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé ní Aramoko Ekiti
- Wo Sẹ́nétọ̀ tó fẹ́ gbé bùkátọ̀ iléẹ̀kọ́ ìbejì Timithy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
Ifayemi Madru, ẹni ọdun mẹrinlelogun toun naa n gbe ni abule Sotan, Shittu Saheed, ẹni ọdun mejidinlogoji ti Alarugbo ati Samod Sulaiman, ẹni ọdun marundinlogoji toun naa wa ni abule Sotan.
Awọn yoku ni Akanji Moruf, ẹni ọdun mẹtalelogun to wa ni abule Alabata ati Tajudeen Adekunle, tii se ẹni ọdun mẹrindinlogoji to n gbe ni adugbo Sapon ni Abeokuta.
Nigba to n salaye bi ọwọ ọlọpaa se tẹ awọn afurasi afinisetutuọla naa, atẹjade naa ni ọkunrin kan, Abraham Okosun lo fi ọrọ lọ agọ ọlọpaa Bode Olude pe wọn pa aburo oun.
Orukọ aburo rẹ naa ni Sunday Okosun, to n gbe ni abule Agbara lọna Mawuko nilu Abeokuta, ti Abraham si ni wọn ge awọn ẹya ara aburo oun lọ lẹyin ti wọn pa tan.
Oyeyemi ni idi ree ti awọn ọlọpaa se bẹrẹ si ni finmu finlẹ nipa isẹlẹ naa, ti ọwọ wọn si tẹ Lekan Oladipupo, ẹni to jẹwọ pe oun ni oun fi ibọn sakabula oun pa ọloogbe naa.
Asiri to tu yii lo mu ki ọlọpaa ri awọn eeyan mẹfa yoku to lọwọ ninu iwa ipaniyan ọhun mu, tawọn mejeeje fi di ero atimọle ọlọpaa.
Lasiko ifọrọwanilẹnuwo si ni ikọọkan afurasi naa jẹwọ pe ipa ti wọn ko ninu ipaniyan naa pẹlu afikun pe Sunday Okosun kii se akọkọ tawọn yoo pa fi se etutu ọla.
Lekan Oladipupo ni ojuse ti toun ni lati wa ẹni ti wọn yoo pa, to si saba maa n waye ninu igbo abule Mawuko, ti oun yoo si fi ibọn ilewọ oun pa.
O ni lẹyin naa ni oun yoo ke si Sulaiman Aremu, ẹni ti yoo kun ẹni ti oun ba pa, ti wọn yoo si yọ awọn ẹya ara rẹ to se koko lati ta fun awọn onibara ti yoo ra wọn fun oogun owo.
Ifayemi Badru ni oun lo ra ọkan, ọwọ atawọn ẹya ara oloogbe mii, Shittu Saheed lo ra ori nigba ti Akanji Moruf ra ọkan oloogbe miran ti wọn pa, Tajudeen Adekunle si lo ra ori onitọun.
Bakan naa ni Oladipupo jẹwọ pe oun ti pa eeyan mẹrin miran tẹlẹ, ti awọn si maa n lo ẹya ara wọn fun oogun owo.
Wọn tun sọ fun ileesẹ ọlọpaa pe awọn ni adape orukọ ti awọn maa n pe ẹya ara kọọkan tawọn ba fẹ ra lọwọ awọn alapata eeyan, ori eeyan si ni awọn maa n pe ni bọọlu.
O ni ọkan ni wọn n pe ni Transformer, eyiun amunawa nigba ti ọwọ si jẹ faanu.
Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole, ti wa se apejuwe isẹlẹ ipaniyan-sowo naa bii iwa ika ati ailaanu, to si pasẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi naa lọ sileesẹ ọlọpaa inu lati sewadi siwaju lori isẹlẹ naa.














