Dudu Heritage Kò sí ń nǹkan tí ó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ, Bimbo Oshin kọ ọrọ ìdárò lẹyin ikú ọkọ rẹ tó d'oloogbe

Dudu Heritage

Oríṣun àwòrán, others

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Bimbo Oshin tí padà sí ojú òpó ikansiraẹni instagram lẹ́yìn oṣù diẹ tó o ti n sọfọ ikú ọkọ rẹ Dudu Heritage

Ọkọ rẹ to kú ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹsàn-án ọdún 2021 tí ọ̀pọ̀ àwọn alabasisẹpọ rẹ sì jáde lójú òpó ikanairaeni láti wá kii kú ará fẹraku

Ìròyìn sọ pé wọn rí Ola Ibironke to jẹ́ ọkọ Bimbo Oshin to ṣubú lulẹ̀ ni ibi tí wón ti ń ṣe eré ìdárayá Gulf ni nnkan bí aago mẹjọ àbọ̀ ọjọ naa n'ilu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ gbogbo ìgbìyànjú láti dáa padà sáyé ló ja sí pàbó, wọ́n sì gbé lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí wọn tí kéde pé ó ti jáde láyé

Nínú alaye gbọọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ ni Bimbo Osun tí sọ pe ko burú ju kí ènìyàn pàdánù olólùfẹ́ ẹni lo, ṣùgbọ́n òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.

Bimbo Oshin ni òun ṣe ìdárò ọkọ òun nígbà gbogbo nítorí ó nira àti pé ó sì ń jọ bí àlá náà ni, ṣùgbọ́n òun mọ pe ibikíbi tí ọkọ òun bá wà yóò fẹ ki inú òun máa dùn ni kí ṣeé láti sọ ìrètí nù

Gbajúgbajà òṣèré náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó dúró tíì lásìkò tí wá nílé òpó tó fi mọ́ orí adé Olubadan àti àwọn gbajúgbajà Òṣèré gbogbo.

Dudu Heritage

Oríṣun àwòrán, @Dudu

Bakan naa lo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn egbe òní Gulf Ibadan ni bí ti o ni ọkọ òun jẹ asoju ẹgbẹ́ wọn kì ó tó di ẹni àkọlẹ bo, fún gbogbo nnkan ti wọn ti nígbà tí ọkọ òun wà láàyè àti ìgbà tí ó kú tán.

Bimbo Oshin dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo awon ẹgbẹ́ òṣèré pátá fún ìfẹ́ àti aduro tí. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Oniwo tí ìlú Ìwọ Oba Rasheed Akanbi "A oni fi iru eyi san funrawa loruko Jesu."

Gbajúgbajà òṣèré náà fi kún pé pẹlu bí gbogbo àwọn ènìyàn ṣe ṣe yìí, òun mọ pe inú ọkọ ohun náà fún sí wọn níbikíbi tí ó bá wà