Kano bride die on wedding day: Mọ̀lẹ́bí obìnrin tó kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́

Iyawo

Ọgbọn ọjọ, Oṣu Kọkanla, ọdun 2021 yii lo yẹ ki Hannatu Yahaya wọ ile ọkọ rẹ gẹgẹ bii iyawo aṣẹṣẹ gbe, ṣugbọn iku ti mu ẹmi rẹ lọ ṣaaju ọjọ naa.

Iroyin iku obinrin naa milẹ titi lori ayelujara to bẹẹ to fi jẹ ibanujẹ fun ọpọ awọn ti wọn ko tilẹ mọ obinrin ọhun ri.

Ileeṣẹ iroyin BBC kan si ọkọ afẹsọna oloogbe naa lati mọ bi ọrọ ṣe jẹ, ohun to sọ ree...

Bi iku Hannatu ṣe waye

Gẹgẹ bii ohun ti ọkọ afẹsọna obinrin naa sọ, ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla lo yẹ ko jẹ ọjọ ti inu oun dun julọ laye, amọ ọjọ naa parade di ọjọ ibanujẹ lẹyin ti oun gbọ iroyin pe iyawo afẹsọna oun ti jade laye.

O ni "Lọjọ ti a n sọ yii, emi pẹlu rẹ ṣi jọjọ sọrọ lori ẹrọ ilewọ fun ọpọ wakati ni imurasilẹ igbeyawo wa."

Ibatan oloogbe naa okunrin, Ayuba Yahaya sọ nipa ohun to ṣẹlẹ ni wakati diẹ ki ọlọjọ to de.

O ni "Bi a ṣe n mura lati mu lọ sile ọkọ rẹ, o ni oyi oju n kọ oun, lẹyin naa lo ṣubu lulẹ ti a si gbe digba-digba lọ sile iwosan."

"Emi ni mo wa ọkọ ti a fi gbe lọ sile iwosan, bi mo ṣe n wa ọkọ lọ ni mo ní imọlara pe ẹmi ti n bọ lẹnu rẹ."

Irọlẹ ọjọ naa gan ni iyawo aṣẹṣẹ gbe naa jade laye lasiko ti wọn n mura lati mu lọ sile ọkọ rẹ tuntun.

Àkọlé fídíò, Ilé tẹ́ẹ rò pé ìjọba Eko fún wa, wọ́n rẹ́ǹtì rẹ̀ ni, a kò tíì rí N1Miliọ̀nù kankan di àsìkò yìí - Iya Jumoke

Awọn ibatan rẹ obinrin, to fi mọ awọn ọrẹ rẹ lo wa pẹlu rẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa waye nitori wọn ti gunlẹ sibẹ ṣaaju fun ayẹyẹ igbeyawo ọhun.

Nigba ti gbogbo wọn yoo fi yọju sile iwosan ti wọn gbe lọ ni iroyin tẹ wọn lọwọ pe o ti jade laye.

Ni ti ilera oloogbe na, Ayuba sọ pe kii ṣe ẹni to maa n ṣaisan, ara rẹ si ji pepe ayafi igba to bẹrẹ si n sọrọ nipa inu to n dun un ni nnkan bii ọsẹ meji ṣeyin.

Ayuba sọ pe "Inu rẹ dun gidi nipa igbeyawo naa, koda o ti n mura lati lọ sile ọkọ rẹ, ṣugbọn ni bayii, ara awọn obi wa ko tii balẹ lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye."

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

"Aisan kankan ko ba oloogbe finra, irọ ni pe o ni aisan ọgbẹ inu, ṣugbọn ohun ti mo mọ ni pe nnkan bii ọsẹ meji sẹyin lo bẹrẹ si n sọ pe inu n dun oun."

Ẹni ọdun mejidinlọgbọn ni Hannatu ki ọlọjọ to de lọjọ igbeyawo rẹ.