Ekiti Governorship Election: Gómìnà Fayemi ní kí òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà fi ipò sílẹ̀

Fayẹmi bá BBC sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi/Facebook

Àkọlé àwòrán, Fayẹmi bá BBC sọ̀rọ̀

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ni ijọba rẹ lati fi ipo silẹ ti wọn ba fẹ du ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti.

Ninu atẹjade gba ọwọ agbẹnusọ fun gomina Fayemi, Yinka Oyebode ni wọn ti fi lede pe Ọjọ Kẹrinla, Osu Kejila ni gomina fun wọn da lati fi ipo silẹ ni ijọba oun.

Oyebode ni gomina gbe igbesẹ naa lọna ati rii pe awọn oṣiṣẹ to wa ni ijọba oun ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lai si magomago.

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

Bakan naa ni wọn fi kun un pe eyi tẹlẹ aṣẹ eto idibo lorilẹede Naijiria, paapaa saaju idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti.

''Lọna ati tẹle aṣẹ Ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu APC ti yoo bẹrẹ idibo abẹle ni Oṣu Kini ọdun 2022, ti idibo sipo gomina naa yoo si waye ni Osu Kẹfa, ọdun 2022 kan naa.''

Lara awọn to wa ni ijọba gomina Fayemi ti awọn eniyan lero wi pe wọn fẹ fu ipo yii ni Akọwe ijọba, Biodun Oyebanji, Adari oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti, Biodun Ọmọlẹyẹ, kọmiṣọnna fun ọrọ awujọ, Bamidele Faparusi ati oluranlọwọ pataki si gomina, Ọjọgbọn Bolaji Aluko laarin awọn miran.