FG Covid-19 Vaccine: Òṣíṣẹ́ ọba tí kò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tàbí ṣe àyẹ̀wò àrùn Covid-19 dèrò ìta lọ́ọ́fìsì

Aworan awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ti mọ ita ọfisi wọn

Ijọba apapọ Naijiria ti bẹrẹ igbesẹ lati fidi asẹ rẹ mulẹ pe k'awọn osisẹ ọba gba abẹrẹ ajẹsara to n dena ajakalẹ arun Coronavirus.

Bẹẹ ba gbagbe, osu kẹwa ọdun yii nijọba apapọ ti kede pe oun ko ni fi aaye gba osisẹ ọba kankan lati wọ inu ọọfisi sisẹ lai gba abẹrẹ ajẹsara.

O si fun awọn osisẹ ọba di ọjọ kinni osu Kejila ọdun 2021 lati lọ gba abẹrẹ ajẹsara naa, bi bẹẹ́ kọ, wọn ko ni gba wọn laaye lati wọle si ọọfisi koowa wọn.

Nibayii ti gbedeke ọjọ naa ti ko, se ni awọn agbofinro duro wa wa wa sawọn ẹnu abawọle sawọn ileesẹ ijọba apapọ nilu Abuja lati dena de awọn osisẹ ọba ti ko gba abẹrẹ ajẹsara lati wọle.

Deede aago mẹfa owurọ ni awọn agbofinro ọhun ti duro, ti wọn si n yẹ iwe ẹri awọn osisẹ ọba wo pe wọn ti gba abẹrẹ ajẹsara.

Bakan naa ni wọn n se ayẹwo iwe ẹri ayẹwo arun Covid-19 tawọn osisẹ ti ko ba tii gba abẹrẹ se, eyi ti yoo fidi rẹ mulẹ pe wọn ko ni arun naa.

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

Iru ayẹwo yii si ni wọn ti gbọdọ se, o pẹ tan, ọjọ mẹta sẹyin.

Ọpọ eeyan ni awọn agbofinro naa ti ti mọ ita ọọfisi wọn lai jẹ ki wọn wọle sinu ọgba ileesẹ ijọba lati sisẹ nitori pe wọn ko gba abẹrẹ ajẹsara tabi se ayẹwo ara wọn lati mọ bi wọn ba ni arun naa.

Ijọba ti gbe ibudo kan kalẹ si ẹba ẹnu ọna abawọle sileesẹ ijọba apapọ fun awọn eeyan ti ko tii gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lati se bẹẹ.

Aworan awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn n gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19
Aworan awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ti mọ ita ọfisi wọn
Aworan awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn ti mọ ita ọfisi wọn

Igbesẹ naa si lo n waye nibayii ti ibẹru bojo gbalẹ kan lori ọwọja arun Coronavirus to lekan si pẹlu ẹda arun naa tuntun mii, Omicron, to tun yọju sita.

Ileesẹ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria si ti kede pe eeyan mẹta lo ti fidi mulẹ pe wọn ti ko ẹda arun Coronavirus tuntun naa lorilẹede yii.

Wayi o, Orilẹede Canada si ti fofin de awọn orilẹede kan nilẹ Afirika, to fi mọ Naijiria, lati mase wọle si orilẹede wọn nitori ajakalẹ ẹda arun Coronavirus tuntun, ti wọn pe ni Omicron.