Boat Accident: Bàbá tó pàdánù ọmọ méjì nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní Kano sọ ìrírí rẹ̀

Aworan baba to padanu ọmọ meji

Agba adura ni pe ki abiyamọ ma foju sunkun ọmọ.

Baba kan ni Kano,Mallam Dauda Badau,ni ibanujẹ dori rẹ kodo lẹyin tawọn ọmọ rẹ meji padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi to danu lodo Bagwai.

O ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin BBC pe oun ti ri oku ọkan ninu awọn ọmọ yi to si ku ẹlẹẹkeji toun n reti.

Awọn ọmọ rẹ mejeeji, Sani, ọmọ ọdun mẹrinla ati Umar ọmọ ọdun mẹwaa, wa lara awọn ọmọ ile kewu to lọ kopa ninu etokan labule to wa lẹgbẹ wọn.

Aworan awọn eeyan leti odo ti ọkọ ti danu

Lowurọ ọjọ Iṣẹgun ni iroyin gbode pe ọpọ eeyan lo tẹri sodo yi nigba ti ọkọ oju omi wọn danu.

Awọn alaṣẹ sọ pe awọn ti ri oku eeyan meje to fi mọ awọn mọkandinlogun ti wọn ri yọ lọjọ Iṣgun.

O ṣju mi koro ni ẹru to pọ ju ọkọ naa lo mu ko danu sodo.

Mallam Dauda sọ pe oun gba pe ẹru lo pọ ju ọkọ naa lọ ni tootọ.

''Mo gba bẹẹ lootọ. Yatọ si eeyan mọkandinlaadọta ti ọkọ naa gbe, niṣe lo tun gbe ọpọ apo anamọ pẹlu''

Nipa awọn ọmọ rẹ to ba iṣẹlẹ naa lọ, o sọ pe ''Sani nikan lo yẹ ko lọ ṣugbọn nigba ti ẹkun aburo rẹ pọ ni mo ba ni ko tẹle.''

''Ọwọ ara mi ni mo fi san N350 tawọn ọmọ mi fi wọ inu ọkọ omi to danu lalae mọ pe nkan ti yoo ṣẹlẹ si wn nuu ni''

Ijọba ipinlẹ Kano ti fi iwe sita lati ba awọn to padanu eeyan ninu iṣẹlẹ naa kẹdun iku wọn yi.

Àkọlé fídíò, 'Èèyàn mi mẹ́ta ló wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó dà nù!'

Bẹẹ lo parọwa sawọn eeyan lati jawọ ninu kiko ero ati ẹru to pọju ninu awọn ọkọ oju omi wọn.

Lọdun 2007 irufẹ iṣẹlẹ yi waye to si mu ẹmi eeyan ọgbọn lọ ni ilu Bagwai to fi mọ iyawo tuntun ti wọn n gbe lọ si ile ọkọ rẹ.